Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 46

Ìṣẹ̀lẹ̀ kan Lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì

Ìṣẹ̀lẹ̀ kan Lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọba tó jẹ lórí ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì ni kò dáa. Áhábù sì wà lára àwọn tó burú jù nínú wọn. Obìnrin abọ̀rìṣà kan tó ń jọ́sìn Báálì ló fẹ́. Jésíbẹ́lì ni orúkọ obìnrin náà. Áhábù àti Jésíbẹ́lì mú kí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà máa jọ́sìn Báálì, wọ́n sì tún pa àwọn wòlíì Jèhófà. Kí ni Jèhófà wá ṣe sọ́rọ̀ náà? Jèhófà rán wòlíì Èlíjà sí Áhábù.

Èlíjà sọ fún Ọba Áhábù pé òjò kò ní rọ̀ ní Ísírẹ́lì torí ìwà búburú tó ń hù. Ohun tí Èlíjà sọ ṣẹ lóòótọ́, kò sí òjò fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́ta, oúnjẹ kankan kò sì hù, ebi wá ń pa àwọn èèyàn náà. Jèhófà tún rán Èlíjà pa dà sọ́dọ̀ Áhábù. Áhábù wá sọ fún un pé: ‘Oníjọ̀gbọ̀n ni ẹ́. Ìwọ lo fa gbogbo wàhálà yìí.’ Èlíjà wá sọ fún un pé: ‘Èmi kọ́ ni mo ní kí òjò má rọ̀, ìwọ lo fà á torí pé Báálì ni ò ń sìn. A máa ṣe ohun kan tó máa jẹ́ ká mọ Ọlọ́run tòótọ́. Kó àwọn èèyàn ilẹ̀ Ísírẹ́lì àti àwọn wòlíì Báálì wá sórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì.’

Bí gbogbo wọn ṣe péjọ pọ̀ sí òkè yẹn, Èlíjà sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ tẹ̀ lé e, àmọ́ tó bá jẹ́ Báálì ni, ẹ tẹ̀ lé e. Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ni pé, kí àwọn wòlíì Báálì tó jẹ́ 450 rú ẹbọ kí wọ́n sì ké pe ọlọ́run wọn, èmi náà máa rú ẹbọ, màá sì ké pe Jèhófà. Ọlọ́run tó bá fi iná jó ẹbọ rẹ̀ ni Ọlọ́run tòótọ́.’ Àwọn èèyàn náà sì gba ohun tó sọ.

Àwọn wòlíì Báálì gbé ẹbọ wọn sílẹ̀, ó wá ku kí Báálì fi iná jó ẹbọ náà. Gbogbo ọjọ́ ni wọ́n fi ń pè é, wọ́n ní: ‘Báálì dá wa lóhùn.’ Nígbà tí Báálì kò dáhùn, Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí í fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, ó ní: ‘Ẹ pariwo gan-an, bóyá ó ń sùn lọ́wọ́, ó sì nílò kí ẹnì kan lọ jí i.’ Ilẹ̀ ń ṣú lọ, àwọn wòlíì Báálì ń pe ọlọ́run wọn, àmọ́ kò sẹ́ni tó dá wọn lóhùn.

Èlíjà ní tiẹ̀ to igi jọ, ó sì gbé ẹran sórí rẹ̀, ó wá da omi lé e lórí. Lẹ́yìn ìyẹn, ó gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, jọ̀wọ́ dá mi lóhùn, kí àwọn èèyàn yìí lè mọ̀ pé ìwọ ni Ọlọ́run tòótọ́.’ Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà mú kí iná já bọ́ láti ọ̀run, ó sì jó ẹbọ náà. Àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé: ‘Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!’ Èlíjà wá sọ pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn wòlíì Báálì yẹn sá lọ, ẹ mú wọn.’ Lọ́jọ́ yẹn, àwọn wòlíì Báálì 450 ni wọ́n pa.

Lẹ́yìn ìyẹn, òjò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣú bọ̀ láti orí òkun, Èlíjà wá sọ fún Áhábù pé: ‘Òjò máa tó rọ̀, tètè máa lọ sílé.’ Bí ojú ọ̀run ṣe ṣú bolẹ̀ nìyẹn, atẹ́gùn bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ gan-an, kí wọ́n tó mọ̀, òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ lójijì. Áhábù fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sáré gan-an. Àmọ́, Jèhófà fún Èlíjà lágbára débi pé ó tún sáré ju kẹ̀kẹ́ náà lọ! Àmọ́, ṣé gbogbo ìṣòro Èlíjà ti wá tán nìyẹn? A máa rí i nínú orí tó kàn.

“Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”​—Sáàmù 83:18