Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 47

Jèhófà Fún Èlíjà Lókun

Jèhófà Fún Èlíjà Lókun

Nígbà tí Jésíbẹ́lì gbọ́ ohun tí Èlíjà ṣe fún àwọn wòlíì Báálì, inú bí i gan-an. Ó wá ránṣẹ́ sí Èlíjà pé: ‘Tó bá máa fi di ọ̀la, ìwọ náà á ti kú bí àwọn wòlíì Báálì tí o pa.’ Àyà Èlíjà wá bẹ̀rẹ̀ sí í já, bó ṣe sá lọ sí aṣálẹ̀ nìyẹn. Ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: ‘Jèhófà, wàhálà yìí ti pọ̀ jù, jẹ́ kí n kú.’ Ló bá sùn lọ sábẹ́ igi kan.

Bí Èlíjà ṣe ń sùn, áńgẹ́lì kan rọra jí i, ó sì sọ fún un pé: ‘Dìde, wá jẹun.’ Èlíjà rí búrẹ́dì kan lórí òkúta tó gbóná, ó sì tún rí kọ́ọ̀bù omi kan. Ó jẹun, ó mu, ó sì pa dà sùn. Nígbà tó yá, áńgẹ́lì náà tún jí i, ó sì sọ fún un pé: ‘Jẹun, torí pé tí ò kò bá jẹun, kò ní ṣeé ṣe fún ẹ láti rìn lọ síbi tí ò ń lọ.’ Torí náà, Èlíjà tún jẹun sí i. Lẹ́yìn ìyẹn, Èlíjà rìn fún ogójì [40] ọjọ́ àti òru títí tó fi dé Òkè Hórébù. Nígbà tó dé ibẹ̀, ó wọ inú àpáta kan, ó sì sùn síbẹ̀. Jèhófà wá bá a sọ̀rọ̀, ó ní: ‘Kí lò ń ṣe níbí, Èlíjà?’ Èlíjà sọ pé: ‘Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti pa ẹ́ tì, wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ rẹ, wọ́n sì ti pa àwọn wòlíì rẹ. Ìyẹn nìkan kọ́ o, wọ́n ti fẹ́ pa èmi náà báyìí.’

Jèhófà wá sọ fún un pé: ‘Lọ dúró sórí òkè yìí.’ Ohun tó kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ ni pé, atẹ́gùn kan fẹ́ lórí òkè yẹn. Lẹ́yìn náà, ilẹ̀ mì, iná sì bẹ̀rẹ̀ sí í jó. Níkẹyìn, Èlíjà gbọ́ ohùn kan tó rọra ń sọ̀rọ̀. Èlíjà wá fi aṣọ bo ojú rẹ̀, ó sì dúró síta àpáta náà. Jèhófà wá bi í pé kí nìdí tí o fi sá lọ. Èlíjà sọ pé: ‘Èmi nìkan ló kù.’ Àmọ́, Jèhófà sọ fún un pé: ‘Ìwọ nìkan kọ́ ló kù. Ẹgbẹ̀rún méje [7,000] èèyàn ló ṣì wà ní Ísírẹ́lì tó ń jọ́sìn mi. Torí náà, lọ kí o sì yan Èlíṣà ṣe wòlíì dípò rẹ.’ Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Èlíjà lọ ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe. Ṣé o rò pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí o bá ṣe ohun tó fẹ́ kí o ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ní báyìí, jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lásìkò tí òjò kò fi rọ̀ yẹn.

“Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.”​—Fílípì 4:6