Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 48

Ọmọkùnrin Opó kan Jíǹde

Ọmọkùnrin Opó kan Jíǹde

Ní àsìkò tí òjò kò fi rọ̀ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, Jèhófà sọ fún Èlíjà pé: ‘Lọ sí Sáréfátì. Opó kan tó wà níbẹ̀ máa fún ẹ ní oúnjẹ.’ Nígbà tí Èlíjà dé ẹnu ọ̀nà ìlú yẹn, ó rí opó kan tí ó ń ṣa igi. Èlíjà sọ pé kó fún òun ní omi mu. Bí obìnrin yẹn ṣe fẹ́ lọ gbé omi náà, Èlíjà sọ fún un pé: ‘Jọ̀ọ́, bá mi mú búrẹ́dì wá tí o bá ń bọ̀.’ Àmọ́, opó náà sọ fún un pé: ‘Mi ò ní búrẹ́dì kankan mọ́. Ìyẹ̀fun àti òróró díẹ̀ tí mo fẹ́ fi ṣe búrẹ́dì fún èmi àti ọmọ mi ló kù.’ Èlíjà wá sọ fún un pé: ‘Jèhófà ti ṣèlérí pé tí o bá fún mi ní búrẹ́dì, ìyẹ̀fun àti òróró rẹ kò ní tán títí tí òjò fi máa rọ̀.’

Lẹ́yìn náà, opó yẹn lọ ṣe búrẹ́dì fún Èlíjà. Jèhófà sì mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ torí pé ìyẹ̀fun àti òróró obìnrin náà kò tán, òun àti ọmọ rẹ̀ sì rí oúnjẹ jẹ títí òjò fi bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀.

Àmọ́, nǹkan burúkú kan ṣẹlẹ̀. Ọmọkùnrin opó yẹn ṣàìsàn, ó sì kú. Obìnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Èlíjà pé kó ran òun lọ́wọ́. Èlíjà gba ọmọ náà lọ́wọ́ obìnrin yẹn, ó sì gbé e lọ sí yàrá kan lókè ilé náà. Ó gbé ọmọ náà sórí bẹ́ẹ̀dì, ó sì gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, jọ̀ọ́ jẹ́ kí ọmọ yìí jíǹde.’ Iṣẹ́ ìyanu ńlá ló máa jẹ́ tí Jèhófà bá jí ọmọ náà dìde. Ìdí sì ni pé kò tíì sí ẹnì kankan tó jíǹde rí ṣáájú ìgbà yẹn, àti pé obìnrin náà àti ọmọ rẹ̀ kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì.

Iṣẹ́ ìyanu ńlá kan ṣẹlẹ̀, ọmọ náà jíǹde! Èlíjà wá sọ fún opó náà pé: ‘Wò ó! Ọmọ rẹ ti jíǹde.’ Inú obìnrin náà dùn gan-an, ló bá sọ fún Èlíjà pé: ‘Mo ti wá mọ̀ báyìí pé èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ ni ẹ́ torí pé ohun tí Jèhófà sọ pé kí o sọ nìkan ni ò ń sọ.’

“Ẹ ṣàkíyèsí dáadáa pé àwọn ẹyẹ ìwò kì í fún irúgbìn tàbí kárúgbìn, wọn kò sì ní yálà abà tàbí ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́, síbẹ̀ Ọlọ́run ń bọ́ wọn. Mélòómélòó ni ẹ fi níye lórí ju àwọn ẹyẹ?”​—Lúùkù 12:24