Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 49

Ọlọ́run Fìyà Jẹ Ayaba Búburú Kan

Ọlọ́run Fìyà Jẹ Ayaba Búburú Kan

Lọ́jọ́ kan tí Ọba Áhábù wà lójú wíńdò àáfin rẹ̀ ní Jésírélì, ó rí ọgbà àjàrà kan tó lẹ̀wà tó jẹ́ ti ọkùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Nábótì. Ojú Áhábù wọ ọgbà àjàrà yìí, ó sì fẹ́ kí Nábótì tà á fún òun. Àmọ́ Nábótì kò tà á fún un torí pé òun náà jogún rẹ̀ ni, ó sì lòdì sí Òfin Jèhófà láti ta ilẹ̀ tí èèyàn bá jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. Kàkà kí Áhábù mọrírì ohun rere tí Nábótì ṣe yìí, ṣe ni Áhábù bẹ̀rẹ̀ sí í bínú. Ó bínú gan-an débi pé kò sùn kò sì jẹun.

Àmọ́ Áhábù ní ìyàwọ́ búburú kan ìyẹn Ayaba Jésíbẹ́lì. Jésíbẹ́lì sọ fún Áhábù pé: ‘Ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì. O sì lẹ́tọ̀ọ́ láti ní ohunkóhun tí o bá fẹ́. Mo máa gba ọgbà àjàrà náà fún ẹ.’ Jésíbẹ́lì wá kọ lẹ́tà sí àwọn àgbà ìlú náà pé kí wọ́n parọ́ mọ́ Nábótì pé ó bú Ọlọ́run, kí wọ́n sì pa á. Àwọn àgbààgbà yẹn ṣe ohun tí Jésíbẹ́lì sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe, Jésíbẹ́lì wá sọ fún Áhábù pé: ‘Nábótì ti kú, tètè lọ gba ọgbà àjàrà rẹ̀.’

Nábótì nìkan kọ́ ni aláìṣẹ̀ tí Jésíbẹ́lì pa, ó tún pa àwọn míì tó ń jọ́sìn Jèhófà. Òrìṣà ni òun ń jọ́sìn ní tirẹ̀, iṣẹ́ ibi ló sì máa ń ṣe. Jèhófà rí gbogbo nǹkan burúkú tí Jésíbẹ́lì ṣe. Kí ni Jèhófà wá ṣe sí i?

Lẹ́yìn tí Áhábù kú, Jèhórámù ọmọ rẹ̀ di ọba. Jèhófà wá rán ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jéhù pé kó lọ fìyà jẹ Jésíbẹ́lì àti ìdílé rẹ̀ fún ohun tí wọ́n ṣe.

Jéhù gbéra, ó gun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ lọ sí Jésírélì níbi tí Jésíbẹ́lì ń gbé. Nígbà tí Jèhórámù rí Jéhù lọ́ọ̀ọ́kán, òun náà gun kẹ̀kẹ́ ogun wá pàdé rẹ̀, ó sì bi Jéhù pé: ‘Ṣé àlàáfíà ni?’ Jéhù dáhùn pé: ‘Kò sí àlàáfíà torí pé Jésíbẹ́lì ìyá rẹ ṣì ń hùwà burúkú rẹ̀ lọ.’ Bí Jèhórámù ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó yí pa dà, ó fẹ́ sá lọ. Àmọ́, Jéhù ta ọfà lu Jèhórámù, ó sì kú.

Lẹ́yìn náà, Jéhù forí lé ààfin, nígbà tí Jésíbẹ́lì gbọ́ pé Jéhù ń bọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kun ojú, ó tún irún rẹ̀ ṣe, ó wá dúró síbi wíńdò rẹ̀. Nígbà tí Jéhù dé, Jésíbẹ́lì fìbínú kí i káàbọ̀. Jéhù sì pàṣe fún àwọn ìránṣẹ́ ọba tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésíbẹ́lì pé: “Ẹ gbé e, kí ẹ sì jù ú sí ìsàlẹ̀!” Àwọn ìránṣẹ́ náà gbé Jésíbẹ́lì, wọ́n sì tì í ṣubú láti ojú wíńdò, ó jábọ́ sí ìsàlẹ̀, ó sì kú.

Jéhù tún rí àwọn àádọ́rin [70] míì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Áhábù, ó sì pa wọ́n kó lè mú ìjọsìn òrìṣà Báálì kúrò pátápátá. Ṣé ìwọ náà ti rí i pé Jèhófà mọ ohun gbogbo, tí ó bá tó àkókò lójú rẹ̀, ó máa fìyà jẹ gbogbo ẹni tí ó ń ṣe búburú?

“Ogún ni a ń fi ìwọra kó jọ lákọ̀ọ́kọ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún.”​—Òwe 20:21