Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 51

Jagunjagun àti Ọmọbìnrin Kékeré Kan

Jagunjagun àti Ọmọbìnrin Kékeré Kan

Ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan wà ní ilẹ̀ Síríà, ilẹ̀ yìí sì jìnnà gan-an sí ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Síríà ni wọ́n mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Síríà, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún ìyàwó ọ̀gágun kan tó ń jé Náámánì. Jèhófà ni ọmọbìnrin ń yìí ń jọ́sìn bó tilẹ̀ jẹ́ pé òrìṣà ni àwọn tó wà ní àyíkà rẹ̀ ń bọ.

Ó ṣẹlẹ̀ pé Náámánì ní àìsàn burúkú kan tó máa ń jẹ́ kí ara ro ó. Ó sì wu ọmọbìnrin yìí pé kí òun ran Náámánì lọ́wọ́. Ó wá sọ fún ìyàwó Náámánì pé: ‘Mo mọ ẹnì kan tó lè ran ọkọ yín lọ́wọ́. Ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni ẹni náà wà, wòlíì Jèhófà ni, Èlíṣà sì ni orúkọ rẹ̀. Ó lè wo ọkọ yín sàn.’

Nígbà tí ìyàwó Náámánì sọ ọ̀rọ̀ ọmọbìnrin yìí fún Náámánì, Náámánì pinnu pé òun á lọ sí Ísírẹ́lì lọ bá Èlíṣà. Náámánì rò pé tí òun bá dé Ísírẹ́lì, ó yẹ kí Èlíṣà ṣe òun bí èèyàn pàtàkì. Àmọ́ Èlíṣà kò rí Náámánì sójú, ńṣe ló ní kí ìránṣe òun lọ pàdé Náámánì, kó sì sọ fún un pé: ‘Lọ wẹ̀ nínú Odò Jọ́dánì ní ìgbà méje, àìsàn rẹ yóò sì lọ.’

Ọ̀rọ̀ yìí bí Náámánì nínú gan-an. Ló bá ní: ‘Mo rò pé ńṣe ni wòlíì yìí á gbàdúrà fún mi tí á sì gbé ọwọ́ lé mi lórí, tí ara mi á sì yá. Ó wá ń sọ pé kí n lọ wẹ̀ nínú odò wọn ní Ísírẹ́lì. Ṣèbí a ní odò tó dára ju ìyẹn lọ ní Síríà, kí ló dé tí kò lè sọ pé kí n lọ wẹ̀ níbẹ̀?’ Ọ̀rọ̀ yìí bí Náámánì nínú gan-an débi pé ó fi ìbínú kúrò nílé Èlíṣà.

Ni àwọn ìránṣẹ́ Náámánì bá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Náámánì kó lè ṣe ohun tí ó tọ́. Wọ́n sọ fún un pé: ‘Tó bá jẹ́ pé ohun tí wòlíì yẹn sọ ló máa mú yín lára dá, ó dára kí ẹ ṣe é? Ohun tí wòlíì yìí sì ni kí ẹ ṣe kò le rárá. Kí ló wá dé tí ẹ ò fẹ́ ṣe é?’ Náámánì fetí sí wọn. Ó lọ sí Odò Jọ́dánì, ó sì wẹ̀ níbẹ̀ ní ìgbà méje. Nígbà tí Náámánì máa jáde nínú odò ní ìgbà keje, àìsàn tó ń ṣe é ti lọ. Inú rẹ̀ dùn gan-an, ó sì pa dà lọ dúpẹ́ lọ́wọ́ Èlíṣà. Náámánì ní: ‘Mo ti wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.’ Báwo ló ṣe máa rí lára ọmọbìnrin Ísírẹ́lì yẹn nígbà tó rí i pé ara Náámánì ti yá?

“Láti ẹnu àwọn ìkókó àti àwọn ọmọ ẹnu ọmú ni o ti mú ìyìn jáde.”​—Mátíù 21:16