Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 52

Àwọn Ọmọ Ogun Jèhófà

Àwọn Ọmọ Ogun Jèhófà

Bẹni-Hádádì tó jẹ́ ọba Síríà ti ń gbógun ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àmọ́ kò ráyè ṣẹ́gun ọba Ísírẹ́lì nítorí pé gbogbo ìgbà ni wòlíì Èlíṣà máa ń kọ́ ọba Ísírẹ́lì ní ohun tó máa ṣe kí àwọn ọ̀tá má báa borí rẹ̀. Fún ìdí èyí, Bẹni-Hádádì ọba Síríà wá pinnu pé òun máa jí wòlíì Èlíṣà gbé. Ó gbọ́ pé Èlíṣà wà ní ìlú kan tó ń jẹ́ Dótánì, ló bá rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé kí wọ́n lọ mú un wá.

Nígbà tó máa fi di alẹ́, àwọn ọmọ ogun Síríà ti dé Dótánì. Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì tí ìránṣe Èlíṣà bọ́ síta, ó rí i pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun ti yí ìlú náà ká. Ẹ̀rù bà á, ló bá kígbe pé: ‘Èlíṣà, kí la máa ṣe báyìí?’ Èlíṣà sọ fún un pé: ‘Àwọn tó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tó wà pẹ̀lú wọn lọ.’ Nígbà náà ni Jèhófà la ojú ìránṣẹ́ Èlíṣà, ó sì rí i pé gbogbo òkè ńlá tó yí wọn ká kún fún àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun oníná.

Bí àwọn ọmọ ogun Síríà ṣe fẹ́ wá mú Èlíṣà, Èlíṣà gbàdúrà, ó ní: ‘Jèhófà, jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí wọ́n ríran.’ Lójijì, àwọn ọmọ ogun náà ò mọ ibi tí wọ́n wà mọ́. Wọ́n la ojú wọn sílẹ̀ o, àmọ́ wọn ò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ mọ́. Èlíṣà wá lọ bá wọn, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Ẹ ti ṣìnà, ibi kọ́ ló yẹ kí ẹ wá. Ẹ tẹ̀ lẹ́ mi kálọ, màá mú yín lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ̀ ń wá.’ Wọ́n tẹ̀ lé Èlíṣà títí tí wọ́n fi dé Samaríà, níbi tí ọba Ísírẹ́lì ń gbé.

Ìgbà yẹn lójú wọn tó là. Àmọ́ kò sí ohun tí wọ́n lè ṣe mọ́. Ọba Ísírẹ́lì wá béèrè lọ́wọ́ Èlíṣà pé: ‘Ṣé kí n pa wọ́n?’ Ṣé Èlíṣà wá lo àkókò yìí láti gbẹ̀san lára àwọn ọmọ ogun tó fẹ́ wá jí i gbé? Rárá kò ṣe bẹ́ẹ̀. Èlíṣà sọ pé: ‘Má ṣe pa wọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, fún wọn ní oúnjẹ, kí wọ́n jẹun, kí wọ́n sì máa lọ.’ Ọba wá se oúnjẹ rẹpẹtẹ fún wọn, lẹ́yìn tí wọn jẹun tán, ó sọ pé kí wọ́n máa pa dà lọ sílé wọn.

“Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i, pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.”​—1 Jòhánù 5:14