Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 53

Jèhóádà Kò Bẹ̀rù

Jèhóádà Kò Bẹ̀rù

Jésíbẹ́lì ní ọmọbìnrin kàn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ataláyà, òun náà sì burú bíi Jésíbẹ́lì ìyá rẹ̀. Nígbà yẹn, Ataláyà ni ìyàwó ọba Júdà. Nígbà tí ọkọ rẹ̀ kú, ọmọ rẹ̀ jọba. Àmọ́ nígbà tí ọmọ rẹ̀ kú, Ataláyà sọ ara rẹ̀ di ọba Júdà. Lẹ́yìn náà, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í pa gbogbo ẹni tó yẹ kó jọba, ńṣe ló ń rán àwọn kan kí wọ́n máa pa gbogbo àwọn tó mọ̀ pé wọ́n lè di ọba lọ́la, kódà ó pa àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀. Gbogbo èèyàn wá ń bẹ̀rù rẹ̀.

Nígbà tí Àlùfáà Àgbà tó ń jẹ́ Jèhóádà àti ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Jèhóṣébà rí ìwà burúkú tí Ataláyà ń hù yìí. Wọ́n tètè gbé ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ọmọ Ataláyà tó ń jẹ́ Jèhóáṣì pa mọ́ kí wọ́n má bàa rí i pa. Ohun tí wọ́n ṣe yìí léwu gan-an, síbẹ̀ wọ́n tọ́ ọmọ náà dàgbà nínú tẹ́ńpìlì.

Nígbà tí Jèhóáṣì pé ọmọ ọdún méje, Jèhóádà pe gbogbo ìjòyè àti àwọn ọmọ Léfì, ó wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa ṣọ́ gbogbo ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì ẹ kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé.’ Lẹ́yìn náà ni Jèhóádà wá fi Jèhóáṣì jẹ ọba Júdà, ó sì gbé adé lé e lórí. Gbogbo èèyàn ilẹ̀ Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí í kí ọba, wọ́n sì pariwo pé: ‘Kábíyèsí o, kí adé pẹ́ lórí o!’

Ataláyà gbọ́ ariwo náà, ó sì sáré lọ sí inú tẹ́ńpìlì. Nígbà tó rí i pé wọ́n ti yan ọba tuntun, ó kígbe pé: ‘Áà, ọ̀tẹ̀ rèé o, ọ̀tẹ̀!’ Ni àwọn ìjòyè bá yí ayaba burúkú yìí ká, wọ́n mú un jáde, wọ́n sì pa á. Àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe máa mú kí àwọn ìwà burúkú rẹ̀ dópin?

Ṣe ni Jèhóádà ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́, ó ní kí wọ́n bá Jèhófà ṣe àdéhùn, kí wọ́n sì ṣèlérí fún un pé òun nìkan ni àwọn á máa jọ́sìn. Jèhóádà tún ní kí wọ́n lọ wó gbogbo ilé òrìṣà Báálì, kí wọ́n sì fọ́ àwọn ère wọn sí wẹ́wẹ́. Ó wá yan àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì ṣe kí àwọn èèyàn lè pa dà máa jọ́sìn Ọlọ́run níbẹ̀. Ó tún yan àwọn aṣọ́bodè kí wọ́n máa ṣọ́ tẹ́ńpìlì kí ẹnikẹ́ni tí kò mọ́ má bàa wọlé. Lẹ́yìn gbogbo èyí, Jèhóádà àti àwọn ìjòyè wá mú Jèhóáṣì lọ sí ààfin, wọ́n sì gbé e sórí ìtẹ́ ọba. Inú àwọn èèyàn Júdà dùn gan-an pé àwọn ti bọ́ lọ́wọ́ Ataláyà àti òrìṣà Báálì, ní báyìí, àwọn á lè máa jọ́sìn Jèhófà. Ó dájú pé bí Jèhóádà ṣe jẹ́ onígboyà ló ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́, àbí?

“Ẹ má sì bẹ̀rù àwọn tí ń pa ara ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ọkàn; ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lè pa àti ọkàn àti ara run nínú Gẹ̀hẹ́nà.”​—Mátíù 10:28