Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 54

Jèhófà Ní Sùúrù fún Jónà

Jèhófà Ní Sùúrù fún Jónà

Nígbà kan, àwọn ará Ásíríà ní ìlú Nínéfè ń hùwà tó burú gan-an. Jèhófà wá sọ fún wòlíì rẹ̀ tó ń jẹ́ Jónà pé kó lọ sí Nínéfè, kó sì kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n yí ìwà burúkú wọn pa dà. Àmọ́ kàkà kí Jónà lọ jíṣẹ́, ńṣe ló sá lọ sí ibòmíì. Ó lọ wọ ọkọ̀ ojú omi, ó sì forí lé ìlú kan tó ń jẹ́ Táṣíṣì.

Nígbà tí ọkọ̀ yìí ń lọ lójú omi, atẹ́gùn tó lágbára kan bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ lójú omi, ẹ̀rù sì ba àwọn tó ń wà ọkọ̀ náà. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí àwọn òrìṣà wọn, wọ́n sì béèrè pé: ‘Kí ló dé tí nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀?’ Nígbà tó yá, Jónà sọ fún wọn pé: ‘Èmi ni mo fa gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Torí pé Jèhófà rán mi níṣẹ́ àmọ́ mo sá lọ. Bí ẹ bá fẹ́ kí atẹ́gùn yìí dáwọ́ dúró, ẹ sọ mí sínú òkun yìí.’ Àwọn tó ń wa ọkọ̀ ojú omi náà kò fẹ́ ju Jónà sínú òkun, àmọ́ ó sọ fún wọ́n pé kí wọ́n ju òun sínú omi náà. Nígbà tí wọ́n jù ú sínú òkun, ńṣe ni atẹ́gùn tó lágbára náà wálẹ̀ tí kò sì dà wọ́n láàmú mọ́.

Jónà rò pé òun máa kú bí wọ́n ṣe ju òun sínú omi. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ń lọ sílẹ̀ nínú òkun náà ni ó tún fi ọkàn gbàdúrà sí Jèhófà. Jèhófà wá rán ẹja ńlá kan nínú òkun pé kó gbé Jónà mì, àmọ́ kó má pa Jónà jẹ. Nígbà tí Jónà dé inú ẹja náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: ‘Mo ṣẹ̀lérí pé gbogbo ohun tí o bá ní kí n ṣe ni màá ṣe.’ Jèhófà dá ẹ̀mí Jónà sí nínú ẹja náà fún ọjọ́ mẹ́ta, lẹ́yìn náà ló mú kí ẹja náà pọ Jónà jáde sí orí ilẹ̀ tó gbẹ.

Jèhófà ti gba Jónà là báyìí, ǹjẹ́ ó ṣì máa fẹ́ kí Jónà lọ sí ìlú Nínéfè? Bẹ́ẹ̀ ni. Jèhófà tún sọ fún Jónà pé kí ó lọ sí Nínéfè. Lọ́tẹ̀ yìí, Jónà ṣe ohun tí Jèhófà sọ. Ó lọ síbẹ̀, ó sì sọ fún àwọn èèyàn burúkú náà pé: ‘Ní ogójì [40] ọjọ́ sí i, ìlú Nínéfè máa pa run.’ Bó ṣe sọ̀rọ̀ yìí tán, ẹ jẹ́ mọ̀ pé ṣe ni àwọn ará Nínéfè yí ìwà burúkú wọn pa dà. Ọba ìlú tiẹ̀ sọ fún àwọn ará ìlú pé: ‘Ẹ bẹ Ọlọ́run kí ẹ sì yí pa dà. Bóyá, ó lè ṣàánú wa, kó má pa wá.’ Nígbà tí Jèhófà rí i pé àwọn èèyàn náà ti yí pa dà, kò pa wọn run mọ́.

Ni inú bá bẹ̀rẹ̀ sí í bí Jónà pé Ọlọ́run ò pa ìlú náà run mọ́. Ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí ná, Jèhófà ní sùúrù fún Jónà, ó sì ṣàánú rẹ̀ nígbà tó sá lọ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ṣùgbọ́n Jónà ní tiẹ̀ kò fẹ́ ṣàánú àwọn ará ìlú Nínéfè. Ó fìbínú lọ jókòó sábẹ́ igi kan níwájú ìlú náà, ó wá ṣu ẹnu pọ̀. Kò pẹ́ rárá tí igi náà fi gbẹ, èyí wá túbọ̀ bí Jónà nínú gan-an. Jèhófà wá sọ fún un pé: ‘Ò ń káàánú igi yìí nítorí pé ó gbẹ, àmọ́ o kò fẹ́ sàánú àwọn èèyàn ìlú Nínéfè. Mo káàánú wọn ni mi ò ṣe pa wọ́n run.’ Ẹ̀kọ́ wo ló wà níbẹ̀? Àwọn èèyàn ìlú Nínéfè ṣe pàtàkì ju igi lásán lọ.

“Jèhófà . . . ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”​—2 Pétérù 3:9