Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 57

Jèhófà Rán Jeremáyà Pé Kó Lọ Wàásù

Jèhófà Rán Jeremáyà Pé Kó Lọ Wàásù

Jèhófà yan Jeremáyà láti jẹ́ wòlíì fún àwọn ará ìlú Júdà. Ó ní kó lọ kìlọ̀ fún àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n jáwọ́ nínú ìwà ibi wọn. Jeremáyà sọ pé: ‘Jèhófà, ọmọ kékeré ni mí. Mi ò mọ bí mo ṣe máa bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀.’ Jèhófà wá sọ fún un pé: ‘Má bẹ̀rù. Mo máa kọ́ ẹ ní ohun tí o máa sọ. Màá sì ràn ẹ́ lọ́wọ́.’

Jèhófà sọ fún Jeremáyà pé kó pe àwọn àgbààgbà ìlú náà jọ, kó sì fọ́ ìkòkò mọ́lẹ̀ níwájú wọn, kó wá sọ pé: ‘Bí Jerúsálẹ́mù ṣe máa fọ́ sí wẹ́wẹ́ nìyẹn.’ Àwọn àgbààgbà yìí bínú gan-an nígbà tí Jeremáyà ṣe ohun tí Jèhófà rán an. Àlùfáà kan tó ń jẹ́ Páṣúrì lu Jeremáyà, ó sì de ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú àhámọ́. Ní gbogbo òru yẹn, Jeremáyà ò lè mira. Nígbà tí Páṣúrì tú u sílẹ̀ ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, Jeremáyà sọ pé: ‘Ó tó gẹ́ẹ́, mi ò ṣe mọ́! Mi ò wàásù mọ́.’ Àmọ́, ṣé ó jáwọ́ lóòótọ́? Rárá o. Torí pé nígbà tí Jeremáyà rò ó dáadáa, ó sọ pé: ‘Ńṣe ni ọ̀rọ̀ Jèhófà dà bí iná nínú ara mi. Mi ò lè jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù.’ Jeremáyà sì ń bá a lọ láti máa kìlọ̀ fún àwọn èèyàn náà.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ọba tuntun jẹ ní Júdà. Àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì èké kórìíra Jeremáyà gan-an. Wọ́n sọ fún àwọn ọmọ aládé pé: ‘Ẹ jẹ́ ká pa ọkùnrin yìí.’ Jeremáyà sọ pé: ‘Ẹ kàn fẹ́ pa ẹni tí kò ṣẹ̀ ni, torí pé iṣẹ́ tí Jèhófà rán mi ni mò ń jẹ́, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ara mi.’ Nígbà tí àwọn ọmọ aládé gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sọ pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ́ ká pa ọkùnrin yìí.’

Amọ́ inú ń bí àwọn ọmọ aládé yẹn torí iṣẹ́ ìwàásù tí Jeremáyà ń ṣe. Ni wọ́n bá tún sọ fún ọba pé kó pa Jeremáyà. Ọba sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́. Ni wọ́n bá mú Jeremáyà, wọ́n sì jù ú sínú kànga tí ẹrọ̀fọ̀ wà nínú rẹ̀, wọ́n ronú pé ibẹ̀ ló máa kú sí. Bí Jeremáyà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rì sínú ẹrọ̀fọ̀ nìyẹn.

Ọkùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ààfin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ebedi-mélékì sọ fún ọba pé: ‘Àwọn ọmọ aládé ti ju Jeremáyà sínú kànga! Tí a bá fi sílẹ̀ níbẹ̀, ó máa kú.’ Ọba wá pàṣẹ pé kí Ebedi-mélékì mú àwọn ọkùnrin ọgbọ̀n [30] pẹ̀lú rẹ̀, kí wọ́n sì lọ yọ Jeremáyà kúrò nínú kànga náà. Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà ṣe bíi ti Jeremáyà, tí kò jẹ́ kí ohunkóhun mú kó jáwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù?

“Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn ní tìtorí orúkọ mi; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”​—Mátíù 10:22