Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 62

Ìjọba kan Tó Dà Bí Igi Ńlá

Ìjọba kan Tó Dà Bí Igi Ńlá

Lálẹ́ ọjọ́ kan, Nebukadinésárì lá àlá kan tó bà á lẹ́rù gidigidi. Ó wá pe àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ pé kí wọ́n wá sọ ìtumọ̀ àlá náà fún òun. Àmọ́ kò sí ẹni tó mọ ìtumọ̀ rẹ̀. Níkẹyìn, ọba sọ àlá náà fún Dáníẹ́lì.

Nebukadinésárì sọ fún Dáníẹ́lì pé: ‘Mo rí igi ńlá kan ní ojú àlá. Igi náà ga débi pé ó kan ọ̀run. Kó sì ibi téèyàn wà láyé tí kò ní rí i. Ó ní ewé tó rẹwà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. Àwọn ẹranko máa ń sinmi lábẹ́ rẹ̀, àwọn ẹyẹ sì máa ń kọ́ ilé wọn sórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀. Áńgẹ́lì kan wá sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó sọ pé: “Ẹ gé igi náà lulẹ̀, kí ẹ sì kán ẹ̀ka rẹ̀ da nù. Àmọ́ ṣá o, ẹ fi gbòǹgbò rẹ̀ sílẹ̀ nínú ilẹ̀, kí ẹ sì fi ọ̀já irin àti bàbà dè é yíká. Ọkàn igi náà á sì yí pa dà kúrò ní ti èèyàn sí ti ẹranko, ìgbà méje sì máa kọjá lórí rẹ̀. Kí gbogbo èèyàn lè mọ̀ pé Ọlọ́run ni Alákòóso àti pé ó lè gbé ìjọba fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́.” ’

Jèhófà wá fi ohun tí àlá náà túmọ̀ sí han Dáníẹ́lì. Ẹ̀rù sì ba Dáníẹ́lì gan-an nígbà tó mọ ìtumọ̀ àlá náà. Ó sọ pé: ‘Áà ọba, kò bá dára ká ní àwọn ọ̀tá yín ni àlá náà dá lé lórí, àmọ́ ẹ̀yin ló dá lé. Ẹ̀yin ni igi tí wọ́n gé lulẹ̀ náà. Ìjọba máa bọ́ lọ́wọ́ yín, ẹ sì máa jẹ koríko bíi tí àwọn ẹranko inú igbó. Àmọ́ bí áńgẹ́lì náà ṣe sọ pé kí wọ́n fi gbòǹgbò igi náà sílẹ̀, èyí fi hàn pé ẹ ṣì máa pa dà di ọba.’

Ọdún kan lẹ́yìn náà, Nebukadinésárì ń rìn lórí òkè ààfin rẹ̀, ó sì ń wo bí ìlú Bábílónì ṣe lẹ́wà tó. Ó sọ pé: ‘Ẹ wo ìlú ńlá tí mo fọwọ́ ara mi kọ́. Mo ti di èèyàn ńlá!’ Bó ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ohùn kan láti ọ̀run sọ fún un pé: ‘Nebukadinésárì! A ti gba ìjọba rẹ lọ́wọ́ rẹ.’

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni orí rẹ̀ dàrú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bí ẹranko inú igbó. Èyí mú kí wọ́n lé e kúrò ní ààfin, ó sì lọ ń bá àwọn ẹranko gbé nínú igbó. Irun Nebukadinésárì wá gùn gan-an, èékánná rẹ̀ sì dà bíi ti ẹyẹ àṣá.

Lẹ́yìn ọdún méje, orí Nebukadinésárì pé wálé, Jèhófà sì mú kó pa dà di ọba Bábílónì. Nebukadinésárì wá sọ pé: ‘Mo yin Jèhófà Ọba ọ̀run lógo. Ní báyìí mo mọ̀ pé Jèhófà ni Alákòóso. Ó máa ń rẹ àwọn agbéraga wálẹ̀, ó sì máa ń fi ẹni tó bá wù ú jẹ ọba.’

“Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.”​​—Òwe 16:18