Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 66

Ẹ́sírà Kọ́ Àwọn Èèyàn ní Òfin Ọlọ́run

Ẹ́sírà Kọ́ Àwọn Èèyàn ní Òfin Ọlọ́run

Ó ti tó àádọ́rin [70] ọdún tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti pa dà sí Jerúsálẹ́mù, ṣùgbọ́n àwọn kan ṣì ń gbé àwọn ilẹ̀ tó wà káàkiri Ilẹ̀ Ọba Páṣíà. Ọ̀kan lára wọn ni àlùfáà kan tó ń jẹ́ Ẹ́sírà, tó máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Jèhófà. Ẹ́sírà gbọ́ pé àwọn tó wà ní ìlú Jerúsálẹ́mù kò pa Òfin Ọlọ́run mọ́, ó sì fẹ́ lọ ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọba ilẹ̀ Páṣíà tó ń jẹ́ Atasásítà sọ fún un pé: ‘Ọlọ́run lo fún ẹ lọ́gbọ́n kí o lè kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin rẹ̀. Máa lọ, kí o sì mú ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ bá ẹ lọ dání.’ Ẹ́sírà lọ bá àwọn tó fẹ́ láti pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Wọ́n gbàdúrà pé kí Jèhófà dáàbò bo àwọn lójú ọ̀nà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà.

Lẹ́yìn oṣù mẹ́rin, wọ́n dé Jerúsálẹ́mù. Àwọn ọmọ aládé ibẹ̀ sọ fún Ẹ́sírà pé: ‘Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣàìgbọràn sí Jèhófà, wọ́n lọ fẹ́ àwọn obìnrin tó ń bọ̀rìṣà.’ Kí ni Ẹ́sírà wá ṣe? Níwájú àwọn èèyàn náà, Ẹ́sírà kúnlẹ̀, ó sì gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, ọ̀pọ̀ nǹkan rere lo ti ṣe fún wa, àmọ́ a ti ṣẹ̀ sí ọ.’ Àwọn èèyàn náà ti ronú pìwà dà, àmọ́ wọ́n ṣì ń ṣe ohun tí kò dára. Ẹ́sírà yan àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn onídàájọ́ láti bójú tó ọ̀rọ̀ náà. Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, gbogbo àwọn tí kò sin Jèhófà ni wọ́n lé kúrò.

Ọdún méjìlá kọjá. Láàárín àkókò yẹn, wọ́n tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́. Lẹ́yìn náà, Ẹ́sírà kó àwọn èèyàn náà jọ sí ìta gbangba láti ka Òfin Ọlọ́run fún wọn. Nígbà tí Ẹ́sírà ṣí ìwé náà, àwọn èèyàn náà dìde. Ó yin Jèhófà, àwọn èèyàn náà sì gbé ọwọ́ wọn sókè láti fi hàn pé àwọn fara mọ́ ọn. Lẹ́yìn náà, Ẹ́sírà ka òfin yìí síta, ó sì ń ṣàlàyé rẹ̀. Gbogbo wọn sì ń fetí sílẹ̀. Wọ́n gbà pé àwọn ti ṣẹ̀ sí Jèhófà, wọ́n sì ń sunkún. Ní ọjọ́ kejì, Ẹ́sírà ka púpọ̀ nínu Òfin náà fun wọn. Wọ́n rí i pé ó yẹ kí àwọn ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà láìpẹ́. Lójú ẹsẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í palẹ̀ mọ́ fún àjọyọ̀ náà.

Ní gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àjọyọ̀ náà, wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, wọ́n sì ń yọ̀ torí irè oko wọn dára. Kò tíì sí irú Àjọyọ̀ Àtíbàbà bí èyí láti ìgbà ayé Jóṣúà. Lẹ́yìn àjọyọ̀ náà, àwọn èèyàn náà kóra jọ, wọ́n sì gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, o mú wa kúrò lóko ẹrú, o pèsè fún wa nígbà tí a wà ní aginjù, o sì fún wa ní ilẹ̀ dáradára yìí. Síbẹ̀, léraléra là ń ṣẹ̀ sí ọ. O rán àwọn wòlíì sí wa láti kìlọ̀ fún wa, àmọ́ a ò fetí sílẹ̀. Síbẹ̀, ò ń ṣe sùúrù fún wa. O mú ìlérí tí o ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ. Àwa náà ń ṣèlérí báyìí pé a máa ṣe ohun tí o fẹ́.’ Wọ́n kọ ìlérí wọn sílẹ̀, àwọn ọmọ aládé, àwọn ọmọ Léfì àti àwọn àlùfáà sì fọwọ́ sí i.

“Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”​—Lúùkù 11:28