Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 68

Èlísábẹ́tì Bí Ọmọ Kan

Èlísábẹ́tì Bí Ọmọ Kan

Lẹ́yìn irínwó [400] ọdún tí wọ́n tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́, àlùfáà kan tó ń jẹ́ Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì ìyàwó rẹ̀ ń gbé nítòsí ìlú Jerúsálẹ́mù. Ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ṣègbéyàwó, àmọ́ wọn kò tíì bímọ kankan. Lọ́jọ́ kan, bí Sekaráyà ṣe ń sun tùràrí nínú tẹ́ńpìlì, áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì yọ sí i. Ẹ̀rù ba Sekaráyà gan-an, ṣùgbọ́n Gébúrẹ́lì sọ fún un pé: ‘Má bẹ̀rù. Ìròyìn ayọ̀ ni mo mú wá fún ẹ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Èlísábẹ́tì ìyàwó rẹ máa bí ọmọkùnrin kan, orúkọ rẹ̀ á sì máa jẹ́ Jòhánù. Jèhófà ti yan Jòhánù fún iṣẹ́ pàtàkì kan.’ Sekaráyà béèrè pé: ‘Báwo ni màá ṣe gbà ẹ́ gbọ́? Èmi àti ìyàwó mi ti darúgbó, a ò sì lè bímọ mọ́.’ Gébúrẹ́lì wá sọ pé: ‘Ọlọ́run ló rán mi láti wá sọ̀rọ̀ yìí fún ẹ. Ṣùgbọ́n nítorí pé o kò gbà mí gbọ́, o kò ní lè sọ̀rọ̀ títí ìyàwó rẹ á fi bí ọmọ náà.’

Sekaráyà pẹ́ nínú tẹ́ńpìlì lọ́jọ́ yìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Nígbà tó fi máa jáde, àwọn tó dúró níta fẹ́ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. Àmọ́, Sekaráyà ò lè sọ̀rọ̀. Ńṣe ló kàn ń fọwọ́ ṣàpèjúwe. Ìgbà yẹn ni àwọn èèyàn tó mọ̀ pé Sekaráyà tí gbọ́ ìròyìn kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Kò pẹ́, Èlísábẹ́tì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan bí áńgẹ́lì náà ṣe sọ. Àwọn ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá wo ọmọ náà. Wọ́n sì ń bá Èlísábẹ́tì yọ̀. Èlísábẹ́tì wá sọ pé: ‘Jòhánù ni orúkọ rẹ̀ á máa jẹ́.’ Àwọn èèyàn náà dá a lóhùn pé: ‘Kò sẹ́ni kankan tó ń jẹ́ Jòhánù nínú ilé yín. Jẹ́ ká máa pè é ní Sekaráyà, bíi ti bàbá rẹ̀.’ Àmọ́, Sekaráyà kọ ọ́ sínú ìwé pé: ‘Jòhánù ni orúkọ rẹ̀.’ Lójú ẹsẹ̀, Sekaráyà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ pa dà! Gbogbo Jùdíà ni wọ́n ti gbọ́ ìròyìn ọmọ náà, àwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé: ‘Kí lọmọ yìí máa dì tó bá dàgbà?’

Ẹ̀mí mímọ́ wá bà lé Sekaráyà. Ó sì sọ tẹ́lẹ̀ pé: ‘Ẹ yin Jèhófà. Ó ṣèlérí fún Ábúráhámù pé Òun máa rán olùgbàlà kan wá, ìyẹn Mèsáyà, láti gbà wá là. Jòhánù máa di wòlíì, á sì pa ọ̀nà mọ́ fún Mèsáyà.’

Ohun pàtàkì kan tún ṣẹlẹ̀ sí ìbátan Èlísábẹ́tì kan tó ń jẹ́ Màríà. A máa mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní orí tó kàn.

“Lọ́dọ̀ ènìyàn, èyí kò ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.”​—Mátíù 19:26