Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 69

Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì Lọ Sọ́dọ̀ Màríà

Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì Lọ Sọ́dọ̀ Màríà

Èlísábẹ́tì ní ìbátan kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Màríà, tó ń gbé ní ìlú Násárétì ní ilẹ̀ Gálílì. Màríà àti Jósẹ́fù tó jẹ́ káfíńtà ń fẹ́ ara wọn sọ́nà. Nígbà tí oyún Èlísábẹ́tì pé oṣù mẹ́fà, áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì lọ sọ́dọ̀ Màríà. Ó sọ pé: ‘Ṣé dáadáa ni, Màríà? Jèhófà ti fi ojú rere hàn sí ẹ.’ Ohun tí áńgẹ́lì náà ń sọ kò yé Màríà. Gébúrẹ́lì wá sọ fún un pé: ‘Ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù. Yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba. Ìjọba rẹ̀ kò sì ní lópin.’

Màríà wá sọ fún un pé: ‘Báwo ni mo ṣe máa bímọ, torí pé mi ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí.’ Gébúrẹ́lì sọ pé: ‘Kò sí ohun tí Jèhófà kò lè ṣe. Ẹ̀mí mímọ́ máa bà lé ẹ, wàá sì bí ọmọkùnrin kan. Èlísábẹ́tì ìbátan rẹ náà ti lóyún.’ Lẹ́yìn náà Màríà sọ pé: ‘Ẹrúbìnrin Jèhófà ni mo jẹ́. Kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti sọ.’

Máríà wá rìnrìn àjò lọ sọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì. Nígbà tí Màríà kí i, Èlísábẹ́tì mọ̀ ọ́n lára pé ọmọ inú òun mira. Ẹ̀mí mímọ́ sì mú kí Èlísábẹ́tì sọ pé: ‘Màríà, Jèhófà ti bù kún ọ. Ojú rere ńlá ló jẹ́ fún mi pé ìyá Olúwa mi wá sí ilé mi.’ Màríà sì sọ pé: ‘Mo fi gbogbo ọkàn mi yin Jèhófà lógo.’ Màríà dúró sọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì fún oṣù mẹ́tà, lẹ́yìn náà, ó pa dà sí ilé rẹ̀ ní Násárétì.

Jósẹ́fù fẹ́ kọ Màríà sílẹ̀ nígbà tó gbọ́ pé ó ti lóyún. Àmọ́, áńgẹ́lì kan yọ sí i lójú àlá, ó sì sọ fún un pé: ‘Ma bẹ̀rù láti gbé Màríà níyàwó. Kò ṣe ohun kankan tó burú.’ Torí náà, Jósẹ́fù gbé Màríà níyàwó, ó sì mú un wá sí ilé rẹ̀.

“Ohun gbogbo tí Jèhófà ní inú dídùn sí láti ṣe ni ó ti ṣe ní ọ̀run àti ní ilẹ̀ ayé.”​—Sáàmù 135:6