Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 70

Àwọn Áńgẹ́lì Kéde Pé Wọ́n Bí Jésù

Àwọn Áńgẹ́lì Kéde Pé Wọ́n Bí Jésù

Alákòóso Ilẹ̀ Ọba Róòmù tó ń jẹ́ Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn Júù pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn láti lọ forúkọ sílẹ̀. Torí náà, Jósẹ́fù àti Màríà rìnrìn àjò lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó jẹ́ ìlú Jósẹ́fù. Ó sì ti tó àsìkò fún Màríà láti bímọ.

Nígbà tí wọ́n dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ibi kan ṣoṣo tí wọ́n rí dúró sí ni ibi tí àwọn ẹran ń sùn sí. Ibẹ̀ ni Màríà bí Jésù sí. Ó wá fi aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ bò ó lára, ó sì rọra tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran.

Àwọn olùṣọ́ àgùntàn kan wà ní pápá, nítòsí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, tí wọ́n ń ṣọ́ àwọn ẹran wọn. Lójijì, áńgẹ́lì kan yọ sí wọn, ìmọ́lẹ̀ ògo Jèhófà sì tàn yí wọn ká. Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà, àmọ́ áńgẹ́lì náà sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má bẹ̀rù. Mo ní ìròyìn ayọ̀ kan fún yín. Wọ́n ti bí Mèsáyà lónìí, ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.’ Bó ṣe sọ̀rọ̀ yìí tán, ọ̀pọ̀lọpọ̀ áńgẹ́lì fara hàn lójú ọ̀run, wọ́n sì ń sọ pé: ‘Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run, aláàfíà fún àwọn ọmọ èèyàn.’ Lẹ́yìn náà, àwọn áńgẹ́lì náà lọ. Kí wá ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà ṣe?

Àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà sọ fún ara wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ ká tètè lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n lọ, wọ́n sì bá Jósẹ́fù àti Màríà pẹ̀lú ọmọ tuntun náà nínú ibùjẹ ẹran.

Ẹnu ya gbogbo àwọn tó gbọ́ ohun tí áńgẹ́lì náà sọ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà. Màríà ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ tí áńgẹ́lì náà sọ fún wọn, kò sì gbà gbé rẹ̀. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà pa dà síbi tí àwọn ẹran wọn wà, wọ́n ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ohun tí wọ́n rí tí wọ́n sì gbọ́.

“Láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni mo ti jáde wá, mo sì wà níhìn-ín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò wá rárá ní ìdánúṣe ara mi, ṣùgbọ́n Ẹni yẹn ni ó rán mi jáde.”​—Jòhánù 8:42