Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 71

Jèhófà Dáàbò Bo Jésù

Jèhófà Dáàbò Bo Jésù

Àwọn ilẹ̀ kan wà lápá ìlà oòrùn ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí àwọn èèyàn ibẹ̀ gbà pé ìràwọ̀ lè darí àwọn. Lálẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ọkùnrin kan láti Ìlà Oòrùn rí ohun tó dà bí ìràwọ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò tó ń lọ lójú ọ̀run, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e. “Ìràwọ̀” náà darí wọn lọ sí Jerúsálẹ́mù. Àwọn ọkùnrin náà wá ń béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn pé: ‘Ibo ni ọmọ tí wọ́n bí tó máa di ọba àwọn Júù wà? A fẹ́ forí balẹ̀ fún un.’

Nígbà tí Hẹ́rọ́dù ọba Jerúsálẹ́mù gbọ́ nípa ọba tuntun yìí, ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ rárá. Ó wá béèrè lọ́wọ́ àwọn olórí àlùfáà pé: ‘Ìlú wo ni wọ́n ti máa bí ọba náà?’ Wọ́n sọ fún un pé: ‘Àwọn wòlíì sọ pé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni.’ Torí náà, Hẹ́rọ́dù sọ fún àwọn ọkùnrin tó wá láti Ìlà Oòrùn náà pé: ‘Ẹ lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, kí ẹ sì wá ọmọ náà. Kí ẹ pa dà wá sọ ibi tó wà fún mi, kí èmi náà lè lọ forí balẹ̀ fún un.’ Àmọ́, irọ́ ló ń pa.

“Ìràwọ̀” náà tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ. Ó sì darí àwọn ọkùnrin náà lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. “Ìràwọ̀” náà wá dúró sórí ilé kan, wọ́n sì wọnú ilé náà. Wọ́n rí Jésù àti Màríà ìyá rẹ̀. Wọ́n forí balẹ̀ fún un ọmọ náà, wọ́n sì fún un ní àwọn ẹ̀bùn wúrà àti oje igi tùràrí àti òjíá. Ṣé Jèhófà ló darí àwọn ọkùnrin yìí lọ sọ́dọ̀ Jésù? Rárá o.

Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, Jèhófà sọ fún Jósẹ́fù lójú àlá pé: ‘Hẹ́rọ́dù fẹ́ pa Jésù. Mú ìyàwó rẹ àti ọmọ rẹ, kí ẹ sì sá lọ sílẹ̀ Íjíbítì. Dúró síbẹ̀ títí dìgbà tí mo bá sọ fún ẹ pé kò sí ewu mọ́.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jósẹ́fù àti ìdílé rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì.

Jèhófà ti kìlọ̀ fún àwọn ọkùnrin tó wá láti Ìlà Oòrùn yẹn pé wọn ò gbọ́dọ̀ pa dà sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù. Inú bí Hẹ́rọ́dù gan-an nígbà tó rí i pé àwọn ọkùnrin yẹn kò pa dà wá. Torí pé kò ṣeé ṣe fún un láti mọ ibi tí Jésù wà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo ọmọkùnrin tó wà lọ́jọ́ orí Jésù nílùú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Àmọ́, wọn ò rí Jésù pa torí pé ó ti wà lọ́nà jíjìn nílẹ̀ Íjíbítì.

Nígbà tó yá, Hẹ́rọ́dù kú. Jèhófà wá sọ fún Jósẹ́fù pé: ‘Ní báyìí, o lè pa dà sí ìlú rẹ.’ Bí Jósẹ́fù, Màríà àti Jésù ṣe pa dà sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì nìyẹn, wọ́n sì ń gbé nílùú Násárétì.

“Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí . . . , yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”​—Aísáyà 55:11