Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 72

Nígbà Tí Jésù Wà ní Ọmọdé

Nígbà Tí Jésù Wà ní Ọmọdé

Jósẹ́fù àti Màríà ń gbé ní ìlú Násárétì pẹ̀lú Jésù àti àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn yòókù. Iṣẹ́ káfíńtà ni Jósẹ́fù ń ṣe láti fi gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀, ó sì kọ́ wọn nípa Jèhófà àti Òfin rẹ̀. Ìdílé Jósẹ́fù máa ń lọ sí sínágọ́gù láti lọ jọ́sìn, wọ́n sì máa ń lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọọdún láti ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá.

Nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá [12], ìdílé rẹ̀ rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù bí wọ́n ti máa ń ṣe. Àwọn èrò tó wá ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá pọ̀ gan-an nínú ìlú yìí. Nígbà tí wọ́n ṣe tán, Jósẹ́fù àti Màríà bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn pa dà sílé, wọ́n ronú pé Jésù wà pẹ̀lú àwọn èèyàn tó kù tí wọ́n jọ ń lọ. Àmọ́ nígbà tí wọ́n wá Jésù láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí wọn, wọn kò rí i.

Ni wọ́n bá pa dà sí Jerúsálẹ́mù, ọjọ́ mẹ́ta gbáko ni wọ́n fi wá Jésù kiri. Nígbẹ̀yìn, wọ́n lọ sí tẹ́ńpìlì. Ibẹ̀ ni wọ́n ti rí Jésù, tó jókòó sáàárín àwọn olùkọ́, tó ń tẹ́tí sí wọn, tó sì ń béèrè àwọn ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání. Èyí wú àwọn olùkọ́ náà lórí débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè lọ́wọ́ Jésù. Àwọn ìdáhùn tí Jésù ń fún wọn sì ń yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n rí i pé ó mọ Òfin Jèhófà dáadáa.

Jósẹ́fù àti Màríà ti dààmú gan-an. Màríà sọ pé: ‘Ọmọ mi, a ti ń wá ẹ káàkiri! Ibo lo wà látọjọ́ yìí?’ Jésù sọ pé: ‘Ṣé ẹ kò mọ̀ pé ilé Bàbá mi ni mo máa wà ni?’

Jésù tẹ̀ lé àwọn òbí rẹ̀ pa dà sí ilé wọn ní ìlú Násárétì. Jósẹ́fù kọ́ Jésù ní iṣẹ́ káfíńtà. Irú èèyàn wo lo rò pé Jésù jẹ́ nígbà tó wà ní ọmọdé? Bí Jésù ṣe ń dàgbà, ọgbọ́n rẹ̀ ń pọ̀ sí i. Ó sì ń rí ojú rere Ọlọ́run àti ti àwọn èèyàn.

“Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.” ​—Sáàmù 40:8