Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 75

Èṣù Dán Jésù Wò

Èṣù Dán Jésù Wò

Lẹ́yìn tí Jésù ṣe ìrìbọmi, ẹ̀mí mímọ́ darí rẹ̀ lọ sí aginjù. Jésù ò jẹ ohunkóhun fún ogójí [40] ọjọ́, ebí wá ń pa á gan-an. Bí Èṣù ṣe wá dán Jésù wò níyẹn, ó sọ fún Jésù pé: ‘Tó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ́ lóòótọ́, sọ fún àwọn òkúta yìí pé kí wọ́n di búrẹ́dì.’ Àmọ́, Jésù fi ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ dá a lóhùn, ó sọ pé: ‘A ti kọ ọ́ pé kì í ṣe oúnjẹ nìkan ló máa jẹ́ ká wà láàyè. A gbọ́dọ̀ máa fetí sí gbogbo ohun tí Jèhófà bá sọ.’

Lẹ́yìn ìyẹn, Èṣù tún sọ fún un pé: ‘Tí ìwọ bá jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run lóòótọ́, fò láti ibi tó ga jù ní tẹ́ńpìlì yìí sí ìsàlẹ̀. Torí a ti kọ ọ́ pé Ọlọ́run á rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti gbé ọ, kí o má bàa ṣubú.’ Jésù tún fi Ìwé Mímọ́ dá a lóhùn, ó sọ pé: ‘A ti kọ ọ́ pé ìwọ kò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run rẹ wò.’

Lẹ́yìn ìyẹn, Sátánì tún fi gbogbo ìjọba ayé yìí han Jésù, àti gbogbo ọrọ̀ àti ògo tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó wá sọ fún un pé: ‘Màá fún ẹ ní gbogbo nǹkan yìí tí o bá jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.’ Jésù wá sọ fún Sátánì pé: ‘Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Torí a ti kọ ọ́ pé, Jèhófà Ọlọ́run nìkan ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn.’

Èṣù kúrò lọ́dọ̀ Jésù, lẹ́yìn náà àwọn áńgẹ̀lì wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n sì fún un ní oúnjẹ. Láti ìgbà yẹn ni Jésù ti ń wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run. Iṣẹ́ tí Jèhófà ní kí Jésù wá ṣe lórí ilẹ̀ ayé nìyẹn. Àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ wọn, torí náà ibi gbogbo tí Jésù bá ń lọ ni àwọn èèyàn máa ń tẹ̀ lé e lọ.

“Nígbà tí [Èṣù] bá ń pa irọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtẹ̀sí-ọkàn ara rẹ̀, nítorí pé òpùrọ́ ni àti baba irọ́.”​—Jòhánù 8:44