Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 76

Jésù Lé Àwọn Tó Ń Tajà Nínú Tẹ́ńpìlì

Jésù Lé Àwọn Tó Ń Tajà Nínú Tẹ́ńpìlì

Ní ọdún 30 Sànmánì Kristẹni, Jésù lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wá sí ìlú yẹn láti wá ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá. Ara nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe nígbà àjọyọ̀ yìí ni pé wọ́n máa ń fi ẹran rúbọ nínú tẹ́ńpìlì. Àwọn kan máa ń mú ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ wá láti ilé, àwọn míì sì máa ń rà á ní Jerúsálẹ́mù.

Nígbà tí Jésù lọ sí tẹ́ńpìlì, ó rí àwọn tó ń ta àgùntàn àti àwọn ẹran míì níbẹ̀. Ńṣe ni àwọn èèyàn yẹn ń pa owó nínú ilé Jèhófà, ẹ ò rí i pé wọn kò bọ̀wọ̀ fún ilé Jèhófà! Kí wá ni Jésù ṣe? Ó fi okùn ṣe ẹgba, ó sì fi lé àwọn ẹran náà jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì. Ó wá da tábìlì àwọn tó ń ṣẹ́ owó nù, owó wọn sì dà sílẹ̀. Jésù sọ fún àwọn tó ń ta ẹyẹ àdàbà níbẹ̀ pé: ‘Ẹ kó nǹkan yìí kúrò níbí! Ẹ má sọ ilé Bàbá mi di ọjà!’

Ẹnu ya àwọn èèyàn sí ohun tí Jésù ṣe yìí. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá rántí àsọtẹ́lẹ̀ kan tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa Mèsáyà pé: ‘Ìtara fún ilé Jèhófà máa jẹ mí run.’

Nígbà tó di ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù tún lé àwọn tó ń tajà kúrò nínú tẹ́ńpìlì. Ìdí sì ni pé Jésù ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọ ilé Bàbá rẹ̀ di ibi ìtajà.

“You cannot be slaves to God and to Riches.”​​—Luke 16:13