Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 79

Jésù Ṣe Ọ̀pọ̀ Iṣẹ́ Ìyanu

Jésù Ṣe Ọ̀pọ̀ Iṣẹ́ Ìyanu

Jésù wá sí ayé kó lè wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ká lè mọ àwọn ohun tí Jésù máa ṣe tó bá di Ọba Ìjọba yẹn, Jèhófà fún un ní ẹ̀mí mímọ́ kó lè ṣe iṣẹ́ ìyanu. Gbogbo àìsàn ni Jésù lè wò. Gbogbo ibi tó bá wà ni àwọn aláìsàn ti máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ran àwọn lọ́wọ́, gbogbo wọn ló sì máa ń wò sàn. Àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn adití ń gbọ́ràn, àwọn arọ ń rìn, kódà Jésù lé ẹ̀mí èṣù jáde lára àwọn èèyàn. Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé etí aṣọ Jésù lásán ni wọ́n fọwọ́ kàn, ara wọn máa yá. Gbogbo ibi tí Jésù bá ń lọ ni àwọn èèyàn máa ń tẹ̀ lé e lọ. Kódà, nígbà tí Jésù fẹ́ dá wà, àwọn èèyàn ò fi í sílẹ̀, síbẹ̀ kò lé wọn lọ.

Nígbà kan, àwọn èèyàn gbé arọ kan wá sí ilé tí Jésù wà. Àmọ́, èrò pọ̀ nínú ilé náà débi pé kò sí ọ̀nà láti wọlé. Torí náà, wọ́n dá ihò sí orí ilé náà, wọ́n sì sọ ọkùnrin náà kalẹ̀ síbi tí Jésù wà. Jésù wá sọ fún ọkùnrin náà pé: ‘Dìde, kí o sì máa rìn.’ Nígbà tí àwọn èèyàn rí i pé ọkùnrin náà ti ń rìn, ẹnu yà wọ́n gan-an.

Jésù tún lọ sínú abúlé kan, ó sì rí àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tó jẹ́ adẹ́tẹ̀. Àwọn ọkùnrin náà dúró sí ọ̀ọ́kán, wọ́n sì ń pariwo pé: ‘Jésù, ṣàánú wa!’ Nígbà yẹn, òfin ò gba àwọn adẹ́tẹ̀ láyè láti sún mọ́ àwọn míì. Jésù wá sọ fún àwọn ọkùnrin náà pé kí wọ́n lọ sí tẹ́ńpìlì bí Òfin Jèhófà ṣe sọ pé kí àwọn adẹ́tẹ̀ máa ṣe tí ara wọn bá ti yá. Bí wọ́n ṣe ń lọ síbẹ̀, ara gbogbo wọn yá. Nígbà tí ọ̀kan lára wọn rí i pé ara òun ti yá, ó pa dà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo. Àbí ẹ ò rí nǹkan, nínú àwọn mẹ́wàá tí Jésù wò sàn, ẹyọ̀ kan péré ló pa dà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

Obìnrin kan tún wà tó ti ń ṣàìsàn fún ọdún méjìlá [12], ó sì ń wá ìwòsàn lójú méjèèjì. Obìnrin náà wá sí àárín èrò níbi tí Jésù wà, ó sì fọwọ́ kan eti aṣọ rẹ̀. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ara rẹ̀ yá. Lẹ́yìn náà, Jésù sọ pé: “Ta ní fọwọ́ kàn mí?” Àyà obìnrin náà já gan-an, àmọ́ ó wá sọ́dọ̀ Jésù, ó sì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un. Jésù wá sọ̀rọ̀ ìtùnú fún ún pé: ‘Ọmọbìnrin, máa lọ ní àlàáfíà.’

Lẹ́yìn ìyẹn, ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jáírù bẹ Jésù pé: ‘Jọ̀wọ́ wá sí ilé mi, ara ọmọbìnrin mi kékeré ò yá gan-an.’ Àmọ́, kí Jésù tó dé ilé Jáírù, ọmọ náà ti kú. Nígbà tó dé ibẹ̀, ó rí i tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sunkún. Jésù wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má sunkún mọ́, ó kàn ń sùn ni.’ Ó wá mú ọwọ́ ọmọ náà dání, ó sì sọ pé: “Ọmọdébìnrin, dìde.” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ọmọ náà dìde, Jésù sì sọ fún àwọn òbí rẹ̀ pé kí wọ́n fún un ní oúnjẹ. Ó dájú pé inú àwọn òbí rẹ̀ máa dùn gan-an!

“Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí mímọ́ àti agbára yàn án, ó sì la ilẹ̀ náà kọjá, ó ń ṣe rere, ó sì ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí Èṣù ni lára; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.”​—Ìṣe 10:38