Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 81

TÌwàásù Lórí Òkè

TÌwàásù Lórí Òkè

Lẹ́yìn tí Jésù yan àwọn àpọ́sítélì méjìlá náà, ó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ó sì lọ síbi tí àwọn èrò rẹpẹtẹ jókòó sí. Àwọn èèyàn náà wá láti Gálílì, Jùdíà, Tírè, Sídónì, Síríà àti àwọn ìlú míì tó wà ní ìsọdá Odò Jọ́dánì. Wọ́n gbé àwọn tó ní oríṣiríṣi àìsàn wá sọ́dọ̀ Jésù àti àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu. Gbogbo wọn ni Jésù sì wò sàn. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù jókòó sí ẹ̀gbẹ́ òkè náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀. Ó sọ àwọn nǹkan tí a gbọ́dọ̀ máa ṣe tí a bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Jèhófà máa tọ́ wa sọ́nà, ká sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́, a ò lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí a kò bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. A gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn, ká sì máa ṣe dáadáa sí wọn títí kan àwọn tó kórìíra wa pàápàá.

Jésù sọ pé: ‘Kì í ṣe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ nìkan ló yẹ kí o nífẹ̀ẹ́, ó yẹ kí o nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ náà, kí o sì máa dárí jì wọ́n. Tí ẹnì kan bá sọ pé o ṣẹ òun, tètè lọ bá a, kí o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó má bínú. Ohun tí o bá sì fẹ́ kí àwọn míì ṣe sí ẹ ni kí ìwọ náà máa ṣe sí wọn.’

Jésù tún sọ pé ká má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ owó ká wa lára jù. Ó sọ pé: ‘Ó sàn kí èèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà ju kí èèyàn jẹ́ olówó lọ. Àwọn olè lè jí owó èèyàn lọ, àmọ́ kò sí ẹni tó lè sọ pé kí èèyàn má di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Ẹ má da ara yín láàmú nípa ohun tí ẹ máa jẹ, ohun tí ẹ máa mu tàbí ohun tí ẹ máa wọ̀. Ẹ wo àwọn ẹyẹ, wọn kò ṣiṣẹ́, àmọ́ Jèhófà máa ń rí i pé wọ́n ní oúnjẹ tó pọ̀ láti jẹ. Tí ẹ bá ń da ara yin láàmú ìyẹn ò ní fi ọjọ́ kan kún iye ọjọ́ tí ẹ máa gbé láyé. Ẹ rántí pé Jèhófà mọ gbogbo ohun tí ẹ nílò.’

Àwọn èèyàn yẹn ò rí ẹni tó sọ̀rọ̀ bíi Jésù rí. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn ò kọ́ wọn ní àwọn ohun tí Jésù kọ́ wọn. Àmọ́, kí ló mú kí Jésù mọ èèyàn kọ́ dáadáa? Ìdí ni pé ohun tí Jèhófà sọ ló ń kọ́ àwọn èèyàn.

“Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.”​—Mátíù 11:29