Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 82

Jésù Kọ́ Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Rẹ̀ Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Gbàdúrà

Jésù Kọ́ Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Rẹ̀ Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Gbàdúrà

Àwọn Farisí máa ń ṣe nǹkan torí kí àwọn èèyàn lè máa yìn wọ́n. Torí kí àwọn èèyàn lè rí wọn ni wọ́n sì ṣe máa ń ṣe nǹkan tó dára. Kódà, wọ́n tún máa ń gbàdúrà ní ìta gbangba. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń há àwọn àdúrà tó gùn sórí, wọ́n á wá máa gba àdúrà yẹn sókè ní ojú ọ̀nà àti nínú sínágọ́gù. Ìdí nìyẹn tí ẹnu fi ya àwọn èèyàn nígbà tí Jésù sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má ṣe gbàdúrà bí àwọn Farisí. Wọ́n rò pé Ọlọ́run á gbọ́ àdúrà wọn torí bí wọ́n ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ púpọ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Tí o bá ń gbàdúrà, Jèhófà lò ń bá sọ̀rọ̀, kì í ṣe èèyàn. Má ṣe máa sọ ohun kan náà ṣáá tí o bá ń gbàdúrà. Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí o sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ gan-an.’

Jésù wá sọ pé, ‘Bó ṣe yẹ kí ẹ máa gbàdúrà nìyí: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”’ Jésù tún sọ fún wọn pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wọn ní oúnjẹ tí wón máa jẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, pé kí Jèhófà dárí jì wọ́n, kí ó sì fún wọn ní àwọn nǹkan míì.

Jésù sọ pé: ‘Ẹ má ṣe dákẹ́ àdúrà. Gbogbo ìgbà ni kí ẹ máa bẹ Jèhófà Bàbá yín pé kí ó fún yín ní àwọn nǹkan rere. Gbogbo òbí ló máa ń fẹ́ ohun tó dáa fún àwọn ọmọ rẹ̀. Torí náà, tí ọmọ rẹ bá ní kí o fún òun ní búrẹ́dì, ṣé wàá fún un ní òkúta? Àbí tí o bá ní kí ó fún òun ní ẹja, ṣé wàá fún un ní ejò?’

Jésù wá sọ ẹ̀kọ́ tí ó fẹ́ kí wọ́n kọ́, ó ní: ‘Tí ẹ̀yin bá mọ bí ẹ ṣe ń fún àwọn ọmọ yín ní ẹ̀bùn rere, mélòómélòó ni Jèhófà, Bàbá yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún yín? Tiyín ni pé kí ẹ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.’ Ṣé o máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù? Àwọn nǹkan wo lo máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ṣe fún ẹ?

“Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín.”​—Mátíù 7:7