Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 86

Jésù Jí Lásárù Dìde

Jésù Jí Lásárù Dìde

Jésù ní àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mẹ́ta tó ń gbé ní Bẹ́tánì. Orúkọ wọn ni Lásárù, Màríà àti Màtá. Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni wọ́n. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí Jésù wà ní òdì kejì Odò Jọ́dánì, Màríà àti Màtá rán àwọn kan sí Jésù pé: ‘Ara Lásárù ò yá gan-an. Jọ̀ọ́, tètè máa bọ̀!’ Àmọ́, Jésù ò lọ nígbà yẹn. Ó dúró fún ọjọ́ méjì, lẹ́yìn ìyẹn ó wá sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: ‘Ẹ jẹ́ ká lọ sí Bẹ́tánì. Lásárù ń sùn, mo sì fẹ́ lọ jí i dìde.’ Àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé oorun ni Lásárù ń sùn, ìyẹn á jẹ́ kí ara rẹ̀ yá.’ Jésù kúkú wá sọ fún wọn pé: ‘Lásárù ti kú.’

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tí Lásárù ti kú ni Jésù tó dé Bẹ́tánì. Àwọn èèyàn sì ti pé jọ láti tu Màríà àti Màtá nínú. Nígbà tí Màtá gbọ́ pé Jésù ti dé, ó sáré lọ bá a. Ó wá sọ pé: ‘Olúwa, ká ní o tètè dé ni, arákùnrin mi kò bá má kú.’ Jésù wá sọ fún un pé: ‘Arákùnrin rẹ máa jí pa dà. Ṣé o gbà mí gbọ́, Màtá? Màtá sọ pé: ‘Mo gbà gbọ́ pé á jí dìde nígbà àjíǹde.’ Jésù wá sọ fún un pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.”

Màtá sáré lọ bá Màríà, ó sì sọ fún un pé: ‘Jésù ti dé.’ Màríà wá sáré lọ bá Jésù, àwọn èrò náà sì tẹ̀ lé e. Ló bá wólẹ̀ fún Jésù, ó sì bú sẹ́kún gan-an. Ó sọ pé: ‘Olúwa, ká ní o tètè de ni, arákùnrin mi kò bá má kú.’ Jésù rí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ń dun Màríà tó, ni Jésù náà bá bú sẹ́kún. Nígbà tí àwọn èrò náà rí i pé Jésù ń sunkún, wọ́n sọ pé: ‘Ẹ ò rí i pé Jésù fẹ́ràn Lásárù gan-an.’ Àmọ́, àwọn kan ń ronú pé: ‘Kí nìdí tí kò fi gba ọ̀rẹ́ rẹ̀ là kó má bàa kú?’ Kí ni Jésù máa ṣe báyìí?

Jésù lọ sí ibi tí wọ́n sin Lásárù sí, òkuta ńlá kan ni wọ́n sì fi dí ibẹ̀. Jésù wá sọ pé: ‘Ẹ yí òkuta náà kúrò.’ Màtá sọ pé: ‘O mà ti pé ọjọ́ mẹ́rin! Á ti máa rùn.’ Síbẹ̀, wọ́n yí òkuta náà kúrò, Jésù wá gbàdúrà pé: ‘Bàbá, mo dúpẹ́ pé ò ń tẹ́tí sí mi. Mo mọ̀ pé gbogbo ìgbà lo máa ń tẹ́tí sí mi, àmọ́ mò ń gbàdúrà sókè kí gbogbo àwọn èèyàn yìí lè mọ̀ pé ìwọ lo rán mi.’ Ó wá pariwo pé: “Lásárù, jáde wá!” Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Ńṣe ni Lásárù jáde wá láti inú ibi tí wọ́n sin ín sí pẹ̀lú gbogbo aṣọ tí wọ́n fi dì í. Jésù wá sọ pé: “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ.”

Púpọ̀ lára àwọn tó rí ohun tí Jésù ṣe yìí bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Àmọ́, àwọn kan lọ sọ ohun tí Jésù ṣe fún àwọn Farisí. Láti ìgbà yẹn lọ, ńṣe làwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n á ṣe pa Lásárù àti Jésù. Bí ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù tó ń jẹ́ Júdásì Ísíkáríótù ṣe yọ́ lọ bá àwọn Farisí nìyẹn, ó wá bi wọ́n pé: ‘Èló ni ẹ máa fún mi tí mo bá ṣe ọ̀nà bí ẹ ṣe máa rí Jésù mú?’ Wọ́n gbà láti fún un ní ọgbọ̀n [30] owó fàdákà, Júdásì sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá bó ṣe máa fa Jésù lé àwọn Farisí lọ́wọ́.

“Ọlọ́run tòótọ́ jẹ́ Ọlọ́run oníṣẹ́ ìgbàlà fún wa; ti Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sì ni àwọn ọ̀nà àbájáde kúrò lọ́wọ́ ikú.” ​—Sáàmù 68:20