Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 87

Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa

Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa

Ọdọọdún ni àwọn Júù máa ń ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe é ni pé kí wọ́n lè máa rántí bí Jèhófà ṣe gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Íjíbítì tó ń fi wọ́n ṣe ẹrú àti bó ṣe mú wọn wá sí Ilẹ̀ Ìlérí. Ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá nínú yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí wọ́n jẹun tán, Jésù sọ pé: ‘Ọ̀kan lára yín máa dà mí.’ Ẹnu ya àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, wọ́n sì bi Jésù pé: ‘Ta ni ẹni náà?’ Jésù sọ pé: ‘Ẹni tí mo bá fún ní búrẹ́dì ni ẹni náà.’ Ó wá fún Júdásì Ísíkáríótù ní búrẹ́dì. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀, Júdásì dìde, ó sì jáde kúrò nínú yàrá náà.

Jésù wá gbàdúrà, ó sì pín búrẹ́dì mélòó kan sí wẹ́wẹ́, ó wá fún àwọn àpọ́sítélì tó kù. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ jẹ búrẹ́dì yìí. Ó dúró fún ara mi tí màá fi rúbọ nítorí yín.’ Lẹ́yìn ìyẹn, ó gbàdúrà sórí wáìnì, ó sì gbé e fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Ó wá sọ pé: ‘Ẹ mu wáìnì yìí. Ó dúró fún ẹ̀jẹ̀ mi tí màá fi rúbọ kí Ọlọ́run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì. Mo ṣe ìlérí fún yín pé ẹ máa jẹ ọba pẹ̀lú mi ní ọ̀run. Ẹ máa ṣe èyí ní ọdọọdún láti fi rántí mi.’ Lónìí, àwa ọmọlẹ́yìn Jésù ṣì máa ń pàdé pọ̀ láti ṣe ìrántí rẹ̀ ní ọdọọdún. Ìpàdé yìí la wá mọ̀ sí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lónìí.

Lẹ́yìn oúnjẹ náà, àwọn àpọ́sítélì tó kù bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn jiyàn nípa ẹni tó máa jẹ́ ọ̀gá láàárín wọn. Jésù wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹni tó máa jẹ́ ọ̀gá láàárín yín ni ẹni tó rí ara rẹ̀ bí ẹni tó kéré jù láàárín yín.’

Jésù tún sọ fún wọn pé: ‘Ọ̀rẹ́ mi ni yín. Gbogbo ohun tí Bàbá mi fẹ́ kí n sọ fún yín ni mò ń sọ fún yín. Láìpẹ́, mo máa pa dà sọ́dọ̀ Bàbá mi ní ọ̀run. Ẹ̀yín ṣì máa wà lórí ilẹ̀ ayé, àmọ́ àwọn èèyàn máa mọ̀ pé ọmọlẹ́yìn mi ni yín tí wọ́n bá rí bí ẹ ṣe nífẹ̀ẹ́ ara yín. Torí náà, ẹ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín bí èmi náà ṣe nífẹ̀ẹ́ yín.’

Lẹ́yìn gbogbo ìyẹn, Jésù gbàdúrà sí Jèhófà pé kó dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. Ó ní kí Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè jọ máa ṣiṣẹ́ pọ̀ ní àlàáfíà. Ó tún gbàdúrà pé kí orúkọ Jèhófà di mímọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kọrin ìyìn sí Jèhófà, wọ́n sì jáde lọ. Àsìkò ti wá tó báyìí tí àwọn èèyàn máa mú Jésù.

“Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nítorí pé Baba yín ti tẹ́wọ́ gba fífi ìjọba náà fún yín.”​—Lúùkù 12:32