Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 88

Wọ́n Mú Jésù

Wọ́n Mú Jésù

Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ rìn gba àárín àwọn àpáta tó wà ní Kídírónì kọjá, wọ́n sì lọ sí Òkè Ńlá Ólífì. Òru ni, òṣùpá sì mọ́lẹ̀ yòò. Nígbà tí wọ́n dé ọgbà Gẹtisémánì, Jésù sọ fún wọn pé: ‘Ẹ dúró síhìn-ín, kí ẹ sì máa ṣọ́nà.’ Jésù wá rìn wọnú ọgbà náà, ó sì kúnlẹ̀. Inú Jésù ò dùn rárá, síbẹ̀ ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ.” Jèhófà wá rán áńgẹ̀lì kan sí i láti fún un lókun. Nígbà tí Jésù pa dà sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì, ó rí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n ń sùn. Ó wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ dìde! Kì í ṣe àsìkò yìí ló yẹ kí ẹ máa sùn! Àkókò ti tó báyìí tí wọ́n máa fi mí lé àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́.’

Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn Júdásì dé, òun ló sì ṣáájú àwọn èrò tí wọ́n kó idà àti igi dání. Ó mọ ibi tí wọ́n ti máa rí Jésù torí pé Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sábà maá ń wá síbẹ̀. Júdásì ti sọ fún àwọn ọmọ ogun yẹn pé òun máa fi Jésù hàn wọ́n láàárín àwọn àpọ́sítélì. Bí wọ́n ṣe dé báyìí, ọ̀dọ̀ Jésù ló lọ tààràtà, ó sì sọ pé: ‘Kú déédéé ìwòyí o, Olùkọ́,’ ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu. Jésù wá sọ fún un pé: ‘Júdásì, ò ń fi ẹnu kò mí lẹ́nu kí wọ́n lè mú mi, àbí?’

Jésù sún mọ́ iwájú, ó sì bi àwọn èrò náà pé: “Ta ni ẹ ń wá?” Wọ́n sọ pé: “Jésù ará Násárétì ni.” Ó wá sọ fún wọn pé: “Èmi ni ẹni náà.” Bó ṣe sọ bẹ́ẹ̀, àwọn èrò náà fà sẹ́yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀. Jésù tún bi wọ́n pé: “Ta ni ẹ ń wá?” Wọ́n sì tún sọ pé: “Jésù ará Násárétì ni.” Jésù wá sọ fún wọn pé: ‘Mo sọ fún yín pé èmi ni ẹ̀ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn ọkùnrin yìí máa lọ.’

Nígbà tí Pétérù rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó fa idà kan jáde, ó sì gé etí Málíkọ́sì, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ àlùfáà àgbà. Àmọ́, Jésù fọwọ́ kan etí ọkùnrin náà, ó sì wò ó sàn. Jésù wá sọ fún Pétérù pé: ‘Dá idà rẹ pa dà sí àyè rẹ̀, nítorí tí o bá ń fi idà jà, idà ni wọ́n máa fi pa ìwọ náà.’ Bí àwọn ọmọ ogun ṣe mú Jésù nìyẹn, wọ́n so ọwọ́ rẹ̀, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sì sá lọ. Àwọn èrò náà mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Ánásì olórí àlùfáà. Ánásì béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè lọ́wọ́ Jésù, ó sì rán an lọ sọ́dọ̀ Káyáfà Àlùfáà Àgbà. Àmọ́, kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn àpọ́sítélì?

“Nínú ayé, ẹ óò máa ní ìpọ́njú, ṣùgbọ́n ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”​—Jòhánù 16:33