Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 89

Pétérù Sọ Pé Òun Ò Mọ Jésù Rí

Pétérù Sọ Pé Òun Ò Mọ Jésù Rí

Nígbà tí Jésù àti àwọn àpọ́sítélì wà ní yàrá òkè tí wọ́n ti jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, Jésù sọ fún wọn pé: ‘Gbogbo yín máa fi mí sílẹ̀ ní alẹ́ òní.’ Pétérù wá sọ pé: ‘Èmi kọ́! Kódà, tí gbogbo àwọn tó kù bá fi ẹ́ sílẹ̀, mi ò ní fi ẹ́ sílẹ̀ láéláé.’ Àmọ́, Jésù sọ fún un pé: ‘Kí àkùkọ tó kọ ní òru yìí, ìgbà mẹ́ta ni wàá sọ pé o kò mọ̀ mí rí.’

Nígbà tí àwọn ọmọ ogun mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Káyáfà, púpọ̀ lára àwọn àpọ́sítélì sá lọ. Àmọ́, méjì lára wọn tẹ̀ lé èrò náà lọ. Pétérù wà lára àwọn méjì náà. Ó tẹ̀ lé wọn wọ inú ọgbà ilé Káyáfà, ó sì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ iná tí wọ́n dá sílẹ̀ kí ara rẹ̀ lè mú ooru. Torí bí ibẹ̀ ṣe mọ́lẹ̀, ọ̀kan lára àwọn obìnrin tó ń ṣe ìránṣẹ́ níbẹ̀ rí ojú Pétérù, ó sì sọ pé: ‘Mo mọ̀ ẹ́! Ọ̀rẹ́ Jésù ni ẹ́!’

Pétérù sọ pé: ‘Rárá o, mi ò kì í ṣe ọ̀rẹ́ Jésù o! Ohun tí ẹ̀ ń sọ kò yé mi.’ Pétérù wá lọ sí ẹnu ọ̀nà ìta. Àmọ́, obìnrin míì tún rí i, ó sì sọ fún àwọn tó wà níbẹ̀ pé: ‘Ọ̀rẹ́ Jésù ni ọkùnrin yìí!’ Pétérù sọ pé: ‘Mi ò tiẹ̀ mọ Jésù rí rárá!’ Ọkùnrin míì níbẹ̀ tún sọ pé: ‘Ọ̀kan lára wọn ni ẹ́! Èdè tí ò ń sọ ti jẹ́ ká mọ̀ pé ará Gálílì ni ẹ́, bíi ti Jésù.’ Àmọ́, ṣe ni Pétérù tún búra pé: ‘Àní sẹ́, mi ò mọ̀ ọ́n rí!’

Bí Pétérù ṣe sọ̀rọ̀ yẹn tán báyìí ni àkùkọ kọ. Jésù yíjú láti wo Pétérù, ojú wọn sì ṣe mẹ́rin. Ó wá rántí ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀, bó ṣe bọ́ sí ìta nìyẹn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún gan-an.

Ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa gbẹ́jọ́ Jésù ní ilé Káyáfà. Wọ́n ti pinnu pé àwọn máa pa Jésù ni, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá irọ́ tí wọ́n máa pa mọ́ Jésù. Àmọ́, wọn kò rí nǹkan kan. Nígbà tó yá, Káyáfà bi Jésù pé: ‘Ṣé Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ́?’ Jésù sọ pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni.’ Káyáfà sọ pé: ‘Kí la tún ń wá. Ọ̀rọ̀ burúkú ni ọkùnrin yìí ń sọ!’ Ìgbìmọ̀ náà wá gbà pé kí wọ́n pa Jésù. Wọ́n fọ́ Jésù létí, wọ́n tu itọ́ sí i lára, wọ́n bo ojú rẹ̀, wọ́n ń gbá a ní ẹ̀ṣẹ́, wọ́n sì ń sọ pé: ‘Tó bá jẹ́ wòlíì ni ẹ́ lóòótọ́, dárúkọ́ ẹni tó gbá ẹ!’

Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n mú Jésù lọ sínú yàrá tí àwọn Sànhẹ́dírìn ti máa ń gbẹ́jọ́, wọ́n sì tún bi í pé: ‘Ṣé Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ́?’ Jésù sọ pé: ‘Ẹ̀yin fúnra yín sọ pé Ọmọ Ọlọ́run ni mí.’ Bí wọ́n ṣe fẹ̀sùn kàn án pé ó sọ̀rọ̀ burúkú nìyẹn, wọ́n wá mú un lọ sí ààfin Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ gómìnà Róòmù. Àmọ́, kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?

“Wákàtí náà . . . ti dé, nígbà tí a óò tú yín ká, olúkúlùkù sí ilé tirẹ̀, ẹ ó sì fi èmi nìkan sílẹ̀; síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò wà ní èmi nìkan, nítorí pé Baba wà pẹ̀lú mi.” ​—Jòhánù 16:32