Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 90

Wọ́n Pa Jésù ní Gọ́gọ́tà

Wọ́n Pa Jésù ní Gọ́gọ́tà

Àwọn olórí àlùfáà mú Jésù lọ sí ààfin gómìnà kan tó ń jẹ́ Pílátù. Nígbà tí Jésù débẹ̀, Pílátù bi àwọn àlùfáà náà pé: ‘Ohun búburú wo ni ọkùnrin yìí ṣe?’ Wọ́n dá a lóhùn pé: ‘Ó ń pe ara rẹ̀ ní ọba!’ Pílátù wá bi Jésù pé: ‘Ṣé ìwọ ni Ọba àwọn Júù?’ Jésù dáhùn pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.”

Ni Pílátù bá rán Jésù lọ sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù olùṣàkóso Gálílì, bóyá ó máa mọ ẹ̀ṣẹ̀ tí Jésù ṣẹ̀. Àmọ́ Hẹ́rọ́dù kò rí ohun búburú kankan nípa Jésù, torí náà, ó rán an pa dà sọ́dọ̀ Pílátù. Pílátù wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: ‘Èmi àti Hẹ́rọ́dù kò rí ohun búburú kankan nípa ọkùnrin yìí. Torí náà, màá tú u sílẹ̀ kó máa lọ.’ Àmọ́ àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: ‘Pa á! Pa á!’ Àwọn ọmọ ogun na Jésù lẹ́gba, wọ́n tutọ́ sí i lára, wọ́n sì ń gbá a ní ẹ̀ṣẹ́. Wọ́n tún ṣe adé ẹ̀gún, wọ́n fi dé orí rẹ̀, wọ́n sì fi ṣe yẹ̀yẹ́ pé: ‘Kú déédéé ìwòyí o, ìwọ Ọba àwọn Júù!’ Pílátù tún lọ bá àwọn èèyàn náà, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Èmi kò rí ohun búburú kankan nípa ọkùnrin yìí.’ Ṣùgbọ́n wọ́n tún kígbe pé: “Kàn án mọ́gi!” Torí náà, Pílátù fa Jésù lé wọn lọ́wọ́ láti pa á.

Wọ́n mú Jésù lọ síbì kan tí wọ́n ń pè ní Gọ́gọ́tà, wọ́n kàn án mọ́ òpó igi kan, wọ́n wá gbé igi náà dúró. Jésù wá gbàdúrà pé: ‘Baba, dárí jì wọ́n torí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.’ Àwọn èèyàn ń fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́ pé: ‘Tó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ẹ́, gba ara rẹ là kí o sì bọ́ sílẹ̀ lórí igi yìí.’

Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù sọ fún Jésù pé: “Rántí mi nígbà tí o bá dé inú Ìjọba rẹ.” Jésù sì ṣèlérí fún un pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” Lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn, òkùnkùn ṣú bo gbogbo ilẹ̀ náà fún wákàtí mẹ́ta. Díẹ̀ nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó igi tí wọ́n kan Jésù mọ́, Màríà ìyá Jésù náà wà pẹ̀lú wọn. Jésù wá sọ fún Jòhánù pé kó máa mójú tó Màríà gẹ́gẹ́ bí ìyá rẹ̀.

Níkẹyìn, Jésù sọ pé: “A ti ṣe é parí!” Ó tẹ orí rẹ̀ ba, ó sì kú. Lójijì, ilẹ̀ mì tìtì lọ́nà tó lágbára. Ohun ìyanu kan sì ṣẹlẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì, aṣọ ńlá kan tó wà láàárín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù lọ ya sí méjì látòkè délẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun tó wà níbẹ̀ wá sọ pé: ‘Dájúdájú Ọmọ Ọlọ́run nìyí.’

“Bí ó ti wù kí àwọn ìlérí Ọlọ́run pọ̀ tó, wọ́n ti di ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ nípasẹ̀ rẹ̀.” ​—2 Kọ́ríńtì 1:20