Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 91

Jésù Jíǹde

Jésù Jíǹde

Lẹ́yìn tí Jésù kú, ọkùnrin olówó kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù gba àṣẹ lọ́wọ́ Pílátù láti gbé òkú Jésù kúrò lórí òpó igi náà. Ó wá fi aṣọ tó dára di òkú Jésù, ó sì fi èròjà tó ń ta sánsán sí i, lẹ́yìn náà ló wá tẹ́ Jésù sínú ibojì, ó sì yí òkúta ńlá kan dí ẹnu ibojì náà. Àwọn olórí àlùfáà wá sọ fún Pílátù pé: ‘Ẹ̀rù ń bà wá pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lè wá jí òkú rẹ̀ gbé kí wọ́n sì sọ pé ó ti jíǹde.’ Torí náà, Pílátù sọ fún wọn pé: ‘Ẹ dí ibojì náà, kí ẹ sì fi àwọn ẹ̀ṣọ́ síbẹ̀.’

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, àwọn obìnrin kan wá sí ibojì náà ní àárọ̀ kùtù, wọ́n sì rí i pé wọ́n ti yí òkúta ńlá tó dí ẹnu ibojì náà kúrò. Nígbà tí wọ́n wọ inú ibojì náà, áńgẹ́lì kan sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má bẹ̀rù. Jésù ti jíǹde. Ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n lọ pàdé rẹ̀ ní Gálílì.’

Màríà Magidalénì sáré lọ wá Pétérù àti Jòhánù. Ó wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹnì kan ti wá gbé òkú Jésù o!’ Ni Pétérù àti Jòhánù bá sáré lọ sí ibojì náà. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọn kò bá òkú Jésù níbẹ̀, wọ́n wá pa dà sí ilé wọn.

Nígbà tí Màríà pa dà sí ibojì náà, ó rí áńgẹ́lì méjì nínú ibẹ̀, ó wá sọ fún wọn pé: ‘Mi ò mọ ibi tí wọ́n gbé Olúwa mi lọ.’ Lẹ́yìn náà, ó rí ọkùnrin kan, ó sì rò pé ẹni tó ń ṣọ́ ọgbà ni. Ó wá sọ fún ẹni náà pé: ‘Ẹ jọ̀ọ́ sà, ẹ sọ ibi tí ẹ gbé òkú Jésù lọ fún mi.’ Àmọ́ bí ọkùnrin náà ṣe sọ pé, “Màríà!” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Màríà mọ̀ pé Jésù ni. Ló bá pariwo pé: “Olùkọ́!” ó sì dì mọ́ ọn. Jésù wá sọ fún un pé: ‘Lọ sọ fún àwọn arákùnrin mi pé o ti rí mi.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Màríà sáré lọ bá àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, ó sì sọ fún wọn pé òun ti rí Jésù.

Lọ́jọ́ yẹn, àwọn ọmọlẹ́yìn méjì ń rìnrìn àjò láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Ẹ́máọ́sì. Ṣàdédé ni ọkùnrin kan dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìrìn náà, ó sì béèrè pé kí ni wọ́n ń sọ. Àwọn ọmọlẹ́yìn náà dá a lóhùn pé: ‘Ṣé o kò tíì gbọ́ ni? Àwọn olórí àlùfáà pa Jésù ní ìjẹta. Àmọ́ a gbọ́ táwọn obìnrin kan ń sọ pé ó ti jíǹde!’ Ni ọkùnrin yìí bá bi wọ́n pé: ‘Ǹjẹ́ ẹ gba ohun táwọn wòlíì sọ gbọ́? Wọ́n ní Kristi máa kú ṣùgbọ́n ó máa jí dìde.’ Lẹ́yìn ìyẹn, ọkùnrin náà ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún wọn. Nígbà tí wọ́n dé Ẹ́máọ́sì, àwọn ọmọlẹ́yìn náà sọ fún ọkùnrin yẹn pé kó wá bá àwọn jẹun. Nígbà tí ọkùnrin náà gbàdúrà sórí búrẹ́dì tí wọ́n fẹ́ jẹ ni wọ́n wá mọ̀ pé Jésù ni. Bó ṣe lọ nìyẹn tí wọ́n o sì rí i mọ́.

Àwọn ọmọlẹ́yìn méjèèjì wá sáré lọ sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn àpọ́sítélì níbi tí wọ́n kóra jọ sí ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí wọ́n wà nínú ilé kan níbẹ̀, Jésù yọ sí gbogbo wọn lójijì. Ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ń lá àlá. Jésù sọ fún wọn pé: ‘Ẹ wo ọwọ́ mi, ẹ fọwọ́ kàn mí. Ìwé Mímọ́ ti sọ pé Kristi máa jí dìde.’

“Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” ​—Jòhánù 14:6