Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 92

Jésù Fara Han Àwọn Apẹja

Jésù Fara Han Àwọn Apẹja

Lẹ́yìn ọjọ́ tí Jésù fara han àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, Pétérù lọ sí òkun Gálílì láti lọ pẹja. Tọ́másì, Jákọ́bù, Jòhánù àtàwọn ọmọlẹ́yìn míì sì tẹ̀ lé e lọ. Wọ́n wá ẹja láti alẹ́ mọ́jú, àmọ́ wọn kò rí ẹja kankan pa.

Nígbà tó di àárọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, wọ́n rí ọkùnrin kan tó dúró létí òkun. Ọkùnrin náà wá béèrè lọ́wọ́ wọn pé: ‘Ṣé ẹ rí ẹja pa?’ Wọ́n dáhùn pé: “Rárá!” Ọkùnrin náà wá sọ pé: ‘Ẹ ju nẹ́ẹ̀tì yín sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi náà.’ Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni nẹ́ẹ̀tì wọn kún fún ẹja tó pọ̀ gan-an débi pé wọn kò lè fà á sínú ọkọ̀ ojú omi wọn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jòhánù ti rí i pé Jésù ni ọkùnrin tó ń bá wọn sọ̀rọ̀, ló bá pariwo pé: “Olúwa ni!” Pétérù wá bẹ́ sínú omi, ó sì wẹ̀ lọ sí etí òkun láti pàdé Jésù. Àwọn tó kù náà wa ọkọ̀ lọ bá a.

Nígbà tí wọ́n dé etí òkun, wọ́n rí i pé ó ń yan ẹja àti búrẹ́dì lọ́wọ́. Jésù ní kí wọ́n mú díẹ̀ wá nínú ẹja tí wọ́n pa. Lẹ́yìn náà, ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ wá jẹ oúnjẹ àárọ̀ yín.’

Lẹ́yìn tí wọ́n jẹun tán, Jésù béèrè lọ́wọ́ Pétérù pé: ‘Ṣé o fẹ́ràn mi ju iṣẹ́ ẹja pípa lọ?’ Pétérù dáhùn pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.’ Jésù sọ pé: ‘Torí náà máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kékeré.’ Jésù tún béèrè ní ìgbà kejì pé: ‘Pétérù, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?’ Pétérù dáhùn pé: ‘Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.’ Jésù sọ pé: ‘Máa ṣe olùṣọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.’ Jésù tún wá béèrè ní ìgbà kẹta, ó wá sú Pétérù, ó sì sọ pé: ‘Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo. O mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.’ Jésù sọ fún un pé: “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” Jésù tún sọ fún un pé: “Máa bá a lọ ní títọ̀ mí lẹ́yìn.”

“[Jésù] sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn, èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.’ Kíá, ní pípa àwọn àwọ̀n náà tì, wọ́n tẹ̀ lé e.” ​—Mátíù 4:​19, 20