Ẹ̀KỌ́ 93
Jésù Pa Dà sí Ọ̀run
Nígbà tí Jésù wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní Gálílì. Ó pàṣẹ fún wọn pé: ‘Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọlẹ́yìn. Ẹ máa kọ́ wọn ní ohun tí mo ti kọ́ ọ yín, kí ẹ sì batisí wọn.’ Jésù wá ṣèlérí fún wọn pé, ‘òun máa wà pẹ̀lú wọn.’
Láàárín ogójì [40] ọjọ́ lẹ́yìn tí Jésù jí dìde, ó fara han àwọn ọmọlẹ́yìn púpọ̀ ní Gálílì àti Jerúsálẹ́mù. Ó kọ́ wọn ní àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì, ó sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu. Níkẹyìn, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wá bá a ní orí Òkè Ólífì, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Ẹ dúró ní Jerúsálẹ́mù kí ẹ sì máa retí ohun tí Baba ṣèlérí.’
Àmọ́ ohun tó ń sọ kò yé àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Wọ́n bá béèrè pé: ‘Ṣé o ti fẹ́ di Ọba Ísírẹ́lì ni?’ Jésù dáhùn, ó ní: ‘Kò tíì tó àkókò tí Jèhófà yàn fún mi láti di Ọba. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, ẹ̀mí mímọ́ máa fún yín ní agbára, ẹ ò sì máa wàásù nípa mi. Torí náà, ẹ lọ máa wàásù ní Jerúsálẹ́mù, Jùdíà, Samáríà àti àwọn apá ibi tó jìnnà ní orí ilẹ̀ ayé.’
Lẹ́yìn náà, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í gòkè lọ sí ọ̀run títí òfúrufú fi bò ó. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń wò ó lọ àmọ́ wọn kò rí i.
Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọlẹ́yìn kúrò lórí Òkè Ólífì, wọ́n sì lọ sí Jerúsálẹ́mù. Wọ́n máa ń pàdé pọ̀ láti gbàdúrà nínú yàrá kan tó wà lókè ilé. Wọ́n ń dúró de Jésù kó wá sọ ohun tí wọ́n máa ṣe.
“A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14