Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 94

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jésù Gba Ẹ̀mí Mímọ́

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jésù Gba Ẹ̀mí Mímọ́

Ọjọ́ mẹ́wàá [10] lẹ́yìn tí Jésù pa dà sí ọ̀run, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ gba ẹ̀mí mímọ́. Ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni èyí ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ ìlú sì ni àwọn èèyàn ti wá sí Jerúsálẹ́mù láti wá ṣe àjọyọ̀. Nǹkan bí ọgọ́fà [120] àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù kó ara wọn jọ sínú yàrá òkè kan. Lójijì, nǹkan ìyanu kan ṣẹlẹ̀. Ńṣe ni ohun kan tó dà bí iná dúró sí orí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ oríṣiríṣi èdè. Ariwo tó ń dún bí ìgbà tí ìjì ń jà sì kún inú ilé náà.

Àwọn èrò tó wá sí Jerúsálẹ́mù gbọ́ ariwo yìí, wọ́n sì sáré wá sí ilé náà kí wọ́n lè mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Ńṣe ni ẹnu ya gbogbo wọn nígbà tí wọ́n rí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí wọ́n ń sọ oríṣiríṣi èdè. Wọ́n sọ pé: ‘Ṣebí Gálílì ni àwọn èèyàn yìí ti wá. Báwo ló ṣe wá jẹ́ tí wọ́n ń sọ oríṣiríṣi èdè?’

Lẹ́yìn náà, Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù dúró níwájú àwọn èrò náà. Pétérù wá ṣàlàyé fún wọn nípa bí àwọn ọ̀tá ṣe pa Jésù àti bí Jèhófà ṣe jí i dìde. Pétérù sọ pé: ‘Ní báyìí, Jésù ti wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run ní ọ̀run, ó sì ti fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ tó ṣèlérí. Ìdí nìyẹn tí ẹ fi rí àwọn ìṣẹ́ ìyanu yìí.’

Ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ lọ́jọ́ yẹn wọ àwọn èèyàn náà lọ́kàn, wọ́n wá bi í pé: “Kí ni kí àwa ṣe?” Pétérù dáhùn pé: ‘Ẹ ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí a sì batisí yín ní orúkọ Jésù. Ọlọ́run yóò sì fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́.’ Lọ́jọ́ yẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] èèyàn ló ṣe batisí. Láti ìgbà yẹn ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i ní Jerúsálẹ́mù. Ẹ̀mí mímọ́ wá ran àwọn àpọ́sítélì Jésù lọ́wọ́ láti dá ọ̀pọ̀ ìjọ tuntun sílẹ̀ kí wọ́n lè máa kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ní gbogbo nǹkan tí Jésù pa láṣẹ.

“Bí ìwọ bá polongo ‘ọ̀rọ̀ yẹn tí ń bẹ ni ẹnu ìwọ alára’ ní gbangba, pé Jésù ni Olúwa, tí o sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ pé Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú òkú, a ó gbà ọ́ là.”​—Róòmù 10:9