Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 95

Kò Sí Ohun Tó Lè Dá Wọn Dúró

Kò Sí Ohun Tó Lè Dá Wọn Dúró

Ọkùnrin kan wà tí kò lè rìn, ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì ló sì ti máa ń tọrọ owó lójoojúmọ́. Ní ọ̀sán ọjọ́ kan, ó rí Pétérù àti Jòhánù tó ń lọ sí tẹ́ńpìlì. Ó wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fún mi ní ohun tí ẹ bá ní.’ Pétérù dáhùn pé: ‘Mo máa fún ẹ ní ohun tó dára ju owó lọ. Ní orúkọ Jésù, dìde kí o sì máa rìn!’ Pétérù wá fa ọkùnrin náà sókè, ọkùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn! Inú àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ dùn gan-an sí iṣẹ́ ìyanu yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn sì di ọmọlẹ́yìn Jésù.

Àmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí bí àwọn àlùfáà àti àwọn Sadusí nínú gan-an. Torí náà, wọ́n mú àwọn àpọ́sítélì náà, wọ́n sì gbé wọn lọ sí ilé ẹjọ́, wọ́n wá bi wọ́n pé: ‘Ta ló fún yín ní agbára láti wo ọkùnrin yìí sàn?’ Pétérù dáhùn pé: ‘Jésù Kristi tí ẹ pa ló fún wa lágbára.’ Àwọn aṣáájú-ìsìn yẹn wá pariwo mọ́ wọn pé: ‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ nípa Jésù mọ́!’ Àmọ́ àwọn àpọ́sítélì náà dáhùn pé: ‘A kò lè dákẹ́, a gbọ́dọ̀ máa sọ nípa Jésù.’

Nígbà tí wọ́n fi Pétérù àti Jòhánù sílẹ̀, àwọn méjèèjì lọ bá àwọn ọmọlẹ́yìn tó kù, wọ́n sì ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn. Gbogbo wọn wá jọ gbàdúrà pa pọ̀, wọ́n sì bẹ Jèhófà pé: ‘Jọ̀ọ́, fún wa ní ìgboyà ká lè máa bá iṣẹ́ rẹ lọ.’ Jèhófà dáhùn àdúrà wọn, ó fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì ń bá a lọ láti máa wàásù nìṣó, wọ́n tún ń wo àwọn èèyàn sàn. Èyí mú kí ọ̀pọ̀ àwọn míì di ọmọlẹ́yìn Jésù. Àwọn Sadusí wá bẹ̀rẹ̀ sí í jowú wọn débi pé, wọ́n mú àwọn àpọ́sítélì yìí, wọ́n sì jù wọ́n sí ẹ̀wọ̀n. Àmọ́ nígbà tó di òru, Jèhófà rán áńgẹ́lì kan kó lọ tú wọn sílẹ̀ ní ẹ̀wọ̀n, áńgẹ́lì náà wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ pa dà sí tẹ́ńpìlì, kí ẹ sì máa wàásù níbẹ̀.’

Nígbà tó di àárọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn kan wá sí ilé ẹjọ́ Sànhẹ́dírìn, wọ́n sì sọ fún àwọn aṣáájú-ìsìn pé: ‘Ẹ̀wọ̀n náà ṣì wà ní títì pa, àmọ́ àwọn tí ẹ jù síbẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́! Tẹ́ńpìlì ni wọ́n wà tí wọ́n tí ń kọ́ àwọn èèyàn!’ Ni wọ́n bá tún lọ mú àwọn àpọ́sítélì yìí, wọ́n sì gbé wọn wá sí ilé ẹjọ́ Sànhẹ́dírìn. Àlùfáà àgbà wá sọ fún wọn pé: ‘Ṣebí a ti pàṣẹ fún yín pé ẹ kò gbọ́dọ̀ sọ nípa Jésù mọ́!’ Pétérù dáhùn pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”

Inú bí àwọn aṣáájú-ìsìn yìí gan-an débi pé wọ́n fẹ́ pa àwọn àpọ́sítélì náà. Ṣùgbọ́n Farisí kan tó ń jẹ́ Gàmálíẹ́lì dìde, ó sì sọ pé: ‘Ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra o! Ó lè jẹ́ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn ọkùnrin yìí. Kò sì yẹ ká bá Ọlọ́run jà.’ Wọ́n gba ohun tí Gàmálíẹ́lì sọ. Lẹ́yìn náà, wọ́n na àwọn àpọ́sítélì náà lẹ́gba, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, lẹ́yìn náà wọ́n dá wọn sílẹ̀. Àmọ́ àwọn àpọ́sítélì yẹn ò jáwọ́ láìka gbogbo ohun tí wọ́n ṣe. Wọ́n ń bá a lọ láti máa fi ìgboyà wàásù nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé.

“Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” ​—Ìṣe 5:29