Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 96

Jésù Yan Sọ́ọ̀lù

Jésù Yan Sọ́ọ̀lù

Ìlú Tásù ni wọ́n bí Sọ́ọ̀lù sí, ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù sì ni. Farisí tó mọ Òfin àwọn Júù dáadáa ni, ó sì kórìíra àwọn Kristẹni. Ńṣe ló máa ń mú àwọn Kristẹni jáde nílé wọn, tí a sì fi wọ́n sí ẹ̀wọ̀n. Kódà, ìṣojú rẹ̀ báyìí ní àwọn ìkà èèyàn ṣe sọ Sítéfánù ní òkúta títí tó fi kú.

Ó wu Sọ́ọ̀lù pé kó tún lọ fi ìyà jẹ àwọn Kristẹni ní àwọn ìlú míì yàtọ̀ sí Jerúsálẹ́mù. Ó wá sọ fún àlùfáà àgbà pé kó jẹ́ kí òun lọ sí ìlú Damásíkù kí òun lè lọ fi ìyà jẹ àwọn Kristẹni tó wà níbẹ̀. Bí Sọ́ọ̀lù ṣe sún mọ́ ìlú náà, ìmọ́lẹ̀ kan ṣàdédé tàn yòò níbi tó dúró sí, bó ṣe ṣubú sílẹ̀ nìyẹn. Ó wá gbọ́ tí ohùn kan sọ pé: ‘Sọ́ọ̀lù, kí ló dé tí ò ń takò mí?’ Sọ́ọ̀lù dáhùn pé: ‘Ta ni ẹ́?’ Ohùn náà sọ pé: ‘Èmi ni Jésù. Wọ inú ìlú Damásíkù, ibẹ̀ ni wàá ti mọ nǹkan tó yẹ kí o ṣe.’ Nígbà tí Sọ́ọ̀lù dìde, kò ríran mọ́, wọ́n sì fà á lọ́wọ́ wọ inú ìlú náà.

Kristẹni olóòótọ́ kan wà ní ìlú Damásíkù tó ń jẹ́ Ananíà. Jésù sọ fún un nínú ìran pé: ‘Lọ sí ilé Júdásì tó wà ní ojú ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní Títọ́, kí o sì lọ bá Sọ́ọ̀lù níbẹ̀.’ Ananíà wá sọ pé: ‘Olúwa, mo ti gbọ́ nípa ọkùnrin yìí! Òun ló ń ju àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ sí ẹ̀wọ̀n!’ Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: ‘Lọ bá Sọ́ọ̀lù, torí mo ti yàn án láti wàásù ìhìn rere fún ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.’

Nígbà tí Ananíà rí Sọ́ọ̀lù, ó sọ fún un pé: ‘Sọ́ọ̀lù, arákùnrin, Jésù ló rán mi láti wá la ojú rẹ.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í ríran. Ó wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, ó sì di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Sọ́ọ̀lù ṣèrìbọmi, òun náà sì di Kristẹni. Látìgbà yẹn ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nínú sínágọ́gù pẹ̀lú àwọn Kristẹni míì. Fojú inú wo bí ẹnu ṣe máa ya àwọn Júù nígbà tí wọ́n rí i tí Sọ́ọ̀lù ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Jésù. Wọ́n ń sọ pé: ‘Àbí ẹ ò rí nǹkan, ṣebí ọkùnrin yìí ló máa ń fi ìyà jẹ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù?’

Ọdún mẹ́ta ni Sọ́ọ̀lù fi wàásù fun àwọn tó ń gbé ní ìlú Damásíkù. Àmọ́ àwọn Júù kórìíra Sọ́ọ̀lù, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á. Nígbà tí àwọn ọmọlẹ́yìn gbọ́ pé àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti pa Sọ́ọ̀lù, wọ́n ṣe ọ̀nà àbáyọ fún un. Àwọn ọmọlẹ́yìn náà gbé Sọ́ọ̀lù sínú apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kálẹ̀ láti ojú ihò kan lára ògiri kó lè sá kúrò ní ìlú náà.

Nígbà tí Sọ́ọ̀lù dé Jerúsálẹ́mù, ó gbìyànjú láti lọ bá àwọn ọmọlẹ́yìn tó wà níbẹ̀. Àmọ́ ẹ̀rù ń ba àwọn ọmọlẹ́yìn náà. Ọkàn lára wọn tó ń jẹ́ Bánábà wá mú Sọ́ọ̀lù wá sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe bẹ̀rù Sọ́ọ̀lù mọ́ torí ó ti yí pa dà. Sọ́ọ̀lù wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìtara wàásù ìhìn rere pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tó yá, a wá mọ̀ ọ́n sí Pọ́ọ̀lù.

“Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là. Nínú àwọn wọ̀nyí èmi jẹ́ ẹni àkọ́kọ́.”​—1 Tímótì 1:15