Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 97

Kọ̀nílíù Gba Ẹ̀mí Mímọ́

Kọ̀nílíù Gba Ẹ̀mí Mímọ́

Ọ̀gágun Róòmù kan wà ní ìlú Kesaréà tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù. Ẹni pàtàkì ni, àwọn Júù sì bọ̀wọ̀ fun un gan-an bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe Júù. Ó máa ń ṣàánú àwọn tálákà, ó sì máa ń ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Kọ̀nílíù gba Jèhófà gbọ́, ó sì máa ń gbàdúrà sí i déédéé. Ní ọjọ́ kan, áńgẹ́lì kan fara han Kọ̀nílíù, ó sì sọ fún un pé: ‘Ọlọ́run ti gbọ́ àdúrà rẹ. Torí náà, rán àwọn èèyàn lọ sí ìlú Jópà níbi tí Pétérù ń gbé, kí o sì ránṣẹ́ sí i pé kó wá sọ́dọ̀ rẹ.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Kọ̀nílíù rán àwọn ọkùnrin mẹ́ta sí ìlú Jópà. Ìlú Jópà sì jìn tó nǹkan bí ọgbọ̀n [30] máìlì sí Kesaréà.

Láàárín àkókò yẹn ní ìlú Jópà, Pétérù rí ìran kan. Nínú ìran yẹn, ó rí àwọn ẹran tí àwọn Júù kò gbọ́dọ̀ jẹ, ó wá gbọ́ tí ohùn kan sọ fún un pé kó jẹ ẹ́. Pétérù kọ̀, ó ní: ‘Mi ò jẹ ẹran aláìmọ́ rí láyé mi.’ Lẹ́yìn náà, ohùn yẹn sọ fún un pé: ‘Má ṣe pe àwọn ẹran yìí ní aláìmọ́, torí pé Ọlọ́run ti sọ wọ́n di mímọ́.’ Ohùn yẹn tún wá sọ fún Pétérù pé: ‘Àwọn ọkùnrin mẹ́ta wà ní ẹnu ọ̀nà rẹ. Tẹ̀ lé wọn.’ Pétérù lọ sí ẹnu ọ̀nà, ó rí àwọn ọkùnrin náà, ó sì béèrè ohun tí wọ́n fẹ́. Wọ́n dáhùn pé: ‘Ọ̀gágun Róòmù kan tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù ló rán wa wá. Ó sì ní kí o wá sí ilé òun ní Kesaréà.’ Pétérù gba àwọn ọkùnrin náà lálejò, wọ́n sì sun ilé rẹ̀ mọ́jú. Nígbà tó di ọjọ́ kejì, Pétérù bá àwọn ọkùnrin náà lọ sí ìlú Kesaréà, àwọn arákùnrin míì láti Jópà sì tẹ̀ lé e.

Bí Kọ̀nílíù ṣe rí Pétérù tó dé, ńṣe ló tẹrí ba fún un. Àmọ́ Pétérù sọ fún un pé: ‘Dìde! Èèyàn bí i tìẹ lèmi náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Júù kì í wọ ilé àwọn tí kì í ṣe Júù, Ọlọ́run sọ fún mi pé kí n wá sí ilé rẹ. Jọ̀wọ́, kí nìdí tí o fi ránṣẹ́ sí mi.’

Kọ̀nílíù dá Pétérù lóhùn pé: ‘Lọ́jọ́ mẹ́rin sẹ́yìn, mò ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, áńgẹ́lì kan wá sọ fún mi pé kí n ránṣẹ́ sí ọ. Jọ̀wọ́, sọ̀rọ̀ Jèhófà fún wa.’ Pétérù sọ pé: ‘Mo ti wá rí i pé bákan náà ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ràn gbogbo wa. Ó máa ń tẹ́wọ́ gba ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ sìn ín.’ Pétérù wá kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jésù. Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí mímọ́ bà lé Kọ̀nílíù àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ṣe ìrìbọmi.

“Ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù [Ọlọ́run], tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”​—Ìṣe 10:35