Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 101

Wọ́n Gbé Pọ́ọ̀lù Lọ sí Róòmù

Wọ́n Gbé Pọ́ọ̀lù Lọ sí Róòmù

Ìlú Jerúsálẹ́mù ni Pọ́ọ̀lù parí ìrìn-àjò rẹ̀ kẹta sí, torí pé wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sí ẹ̀wọ̀n. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, Pọ́ọ̀lù rí ìran kan níbi tí Jésù ti sọ fún un pé: ‘O máa lọ sí Róòmù, ó sì máa wàásù níbẹ̀.’ Nígbà tó yá, wọ́n gbé Pọ́ọ̀lù kúrò ní Jerúsálẹ́mù lọ sí ìlú Kesaréà, ó sì lo ọdún méjì nínú ẹ̀wọ̀n níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbé ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù lọ sọ́dọ̀ gómìnà tó ń jẹ́ Fẹ́sítọ́ọ̀sì, Pọ́ọ̀lù sọ fún un pé: ‘Ẹ jẹ́ kí Késárì fúnra rẹ̀ ṣe ìdájọ́ mi ní Róòmù.’ Fẹ́sítọ́ọ̀sì wá dáhùn pé: ‘Ọ̀dọ̀ Késárì tí o sọ ni ìwọ yóò lọ.’ Wọ́n wá fi Pọ́ọ̀lù sínú ọkọ̀ ojú omi tó ń lọ sí Róòmù, àwọn arákùnrin méjì, ìyẹn Àrísítákọ́sì àti Lúùkù sì tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù.

Nígbà tí wọ́n wà lórí omi, ìjì ńlá kan bẹ̀rẹ̀ sí í jà, ìjì náà sì jà fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Gbogbo àwọn tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà rò pé àwọn máa kú. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: ‘Áńgẹ́lì kan sọ fún mi nínú àlá pé: “Má bẹ̀rù Pọ́ọ̀lù. Ìwọ àti gbogbo àwọn tí ẹ jọ wà nínú ọkọ̀ ojú omi yìí máa dé Róòmù láyọ̀ àti ní àlàáfíà.” Torí náà, ẹ má bẹ̀rù! Kò sẹ́ni tó máa kú.’

Ọjọ́ mẹ́rìnlá [14] ni ìjì náà fi jà. Nígbà tó yá, wọ́n rí ìlú kan tó ń jẹ́ Málítà. Bí ọkọ̀ ojú omi náà ṣe dé etí òkun ìlú náà, ńṣe ló fọ́ yángá, tó sì bà jẹ́. Àmọ́ kò sẹ́ni tó kú nínú gbogbo àwọn 276 tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi náà. Àwọn kan wẹ̀ nínú omi dé etí òkun, àwọn míì sì di pákó mú títí wọ́n fi dé etí òkun ìlú Málítà. Àwọn èèyàn ìlú Málítà tọ́jú wọ́n dáadáa, wọ́n tiẹ̀ dáná sílẹ̀ fún wọn torí òtútù.

Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, àwọn sójà fi Pọ́ọ̀lù sínú ọkọ̀ ojú omi míì, wọ́n sì gbé e lọ sí Róòmù. Nígbà tó débẹ̀, àwọn ará wá pàdé rẹ̀. Nígbà tó rí wọn, inú rẹ̀ dùn gan-an, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún òun ní agbára. Àwọn sójà wá fi Pọ́ọ̀lù sínú ilé kan, wọ́n sì fi sójà kan síbẹ̀ torí pé wọ́n kò fẹ́ kí ó jáde kúrò nínú ilé náà. Ọdún méjì ni Pọ́ọ̀lù lò níbẹ̀. Tí àwọn èèyàn bá ti wá Pọ́ọ̀lù wá, Pọ́ọ̀lù máa ń wàásù fún wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó sì máa ń kọ́ wọn nípa Jésù Kristi. Pọ́ọ̀lù tún kọ lẹ́tà sí àwọn ìjọ tó wà ní Éṣíà Kékeré àti Jùdíà. Ó dájú pé Jèhófà lo Pọ́ọ̀lù láti wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn níbi gbogbo.

“Lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run, nípa ìfaradà púpọ̀, nípa àwọn ìpọ́njú, nípa àwọn ọ̀ràn àìní, nípa àwọn ìṣòro.”​—2 Kọ́ríńtì 6:4