Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 103

“Kí Ìjọba Rẹ Dé”

“Kí Ìjọba Rẹ Dé”

Jèhófà ṣèlérí pé: ‘Kò ní sí ẹkún àti ìrora mọ́, bákan náà kò ní sí àìsàn àti ikú mọ́. Mo máa nu ẹkún ojú wọn kúrò. Wọn kò sì ní rántí gbogbo àwọn nǹkan búburú tó ti ṣẹlẹ̀ mọ́.’

Jèhófà fi Ádámù àti Éfà sí inú ọgbà Édẹ́nì, ó sì fẹ́ kí wọ́n ní ayọ̀ àti àlàáfíà. Ó yẹ kí wọ́n máa jọ́sìn Ọlọ́run, kí wọ́n sì bímọ kí àwọn èèyàn lè pọ̀ ní ayé. Kí ni Ádámù àti Éfà wá ṣe? Ṣe ni wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà, síbẹ̀ Jèhófà ṣì máa mú kí ayé rí bó ṣe fẹ́. Nínú ìwé yìí, a ti rí i pé gbogbo ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí ló ṣẹ. Ìjọba rẹ̀ sì máa mú ọ̀pọ̀ nǹkan tó dáa wá gẹ́gẹ́ bó ti ṣèlérí fún Ábúráhámù.

Láìpẹ́, Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ àti gbogbo àwọn èèyàn búburú kò ní sí mọ́. Tó bá di ìgbà yẹn, Jèhófà ni gbogbo èèyàn yóò máa sìn. A kò ní ṣe àìsàn mọ́, kò sì sí ẹni tó máa kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo wa máa ní ìlera tó dáa, inú wa á sì máa dùn lójoojúmọ́. Gbogbo ayé máa di Párádísè, a máa ní oúnjẹ tó dára àti ilé tó rẹwà. A tún máa nífẹ̀ẹ́ ara wa, a kò ní máa jà. Kódà a kò ní bẹ̀rù àwọn ẹranko bíi kìnìún, ẹjò àti àwọn míì, àwọn ẹranko náà kò sì ní sá fún wa mọ́.

Inú wa tún máa dùn gan-an nígbà tí Jèhófà bá bẹ̀rẹ̀ sí í jí àwọn tó ti kú dìde. A máa rí àwọn olóòótọ́ bí Ébẹ́lì, Nóà, Ábúráhámù, Sárà, Mósè, Rúùtù, Ẹ́sítérì àti Dáfídì. Gbogbo wa pátá jọ máa ṣiṣẹ́ pọ̀ láti sọ ayé di Párádísè. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tá a máa gbádùn gan-an làá sì máa ṣe nígbà yẹn.

Jèhófà fẹ́ kí ìwọ náà wà níbẹ̀. Wàá túbọ̀ wá mọ Jèhófà ju bí o ṣe mọ̀ ọ́n báyìí lọ. Torí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà lójoojúmọ́, lónìí àti títí láé!

“Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo.”​—Ìṣípayá 4:11