Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ẹ̀yin Onígbàgbọ́ Ẹlẹgbẹ́ Wa Ọ̀wọ́n:

Gbogbo àwa tá à ń jọ́sìn Jèhófà la nífẹ̀ẹ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó dá wa lójú pé àwọn ìtàn inú rẹ̀ pé pérépéré, bákan náà àwọn ìtọ́ni inú rẹ̀ lè ṣe wá láǹfààní ní ìgbésí ayé, èyí sì jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ọmọ aráyé. (Sáàmù 119:105; Lúùkù 1:3; 1 Jòhánù 4:19) Ó wù wá gan-an pé ká ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ àwọn òtítọ́ tó ṣeyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Torí náà, a láyọ̀ láti mú ìwé tuntun yìí jáde, ìyẹn, Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká sọ díẹ̀ nípa rẹ̀.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọdé la dìídì ṣe ìwé yìí fún, síbẹ̀ a lè lò ó láti ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ mọ ohun tó wà nínú Bíbélì. Ó ṣe tán gbogbo èèyàn ni Bíbélì wà fún, torí náà a máa jàǹfààní tó pọ̀ gan-an tá a bá gbé àwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ yẹ̀ wò. Ìdí ni pé àwọn ẹ̀kọ́ náà máa ń fúnni láyọ̀.

Àwọn ìtàn inú Bíbélì la kó jọ sínú ìwé yìí, ó sọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá àwa èèyàn àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. A kọ àwọn ìtàn náà lọ́nà tó rọrùn tó sì ṣe kedere, a tún gbìyànjú láti sọ àwọn ìtàn náà bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ tè léra.

Yàtọ̀ síyẹn, a kọ ọ́ lọ́nà tó fi máa dùn ún kà. A fi àwòrán mèremère kún un, a sì ṣe é lọ́nà tí a fi máa rí bí nǹkan ṣe rí lára àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn, èyí á jẹ́ kó dà bíi pé àwa alára wà níbẹ̀.

Ìwé yìí sọ nípa àwọn èèyàn tí Bíbélì mẹ́nu kàn, ìyẹn àwọn tó ṣègbọràn sí Jèhófà àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí i. Ó sì tún sọ àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ lára wọn. (Róòmù 15:4; 1 Kọ́ríńtì 10:6) Apá mẹ́rìnlá [14] ni ìwé yìí pín sí. Ní ìbẹ̀rẹ̀ apá kọ̀ọ̀kan, a máa rí àkópọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tá a máa kọ́ nínú apá yẹn.

Ẹ̀yin òbí, tí ẹ bá ń ka àwọn ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan fún àwọn ọmọ yín, ẹ máa ṣàlàyé àwòrán inú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, kí ẹ jọ ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n ti mú ẹ̀kọ́ náà jáde. Rí i pé o ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti mọ bí ohun tó kà nínú àwọn ẹ̀kọ́ yẹn ṣe tan mọ́ ohun tó wà nínú Bíbélì. A lè lo ọ̀nà kan náà tá a bá ń kọ́ àgbàlagbà nípa ohun tí Bíbélì dá lé.

À nírètí pé ìwé yìí máa ran tèwetàgbà tó lọ́kàn rere lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n sì fi àwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ sílò ní ìgbésí ayé wọn. Èyí á jẹ́ kí àwọn náà lè dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn àtàtà tó ń jọ́sìn Jèhófà.

Àwa arákùnrin yín,

Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà