Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 2

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 2

Kí ló dé tí Jèhófà fi fi omi pa àwọn èèyàn búburú run láyé àtijọ́? Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn, àwọn kan ń ṣe rere, àwọn míì sì ń ṣe búburú. Bí àpẹẹrẹ, Ádámù, Éfà àti ọmọ wọn tó ń jẹ́ Kéènì yàn láti máa ṣe búburú. Àmọ́ àwọn èèyàn bí Ébẹ́lì àti Nóà yàn láti máa ṣe rere. Ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà yẹn ló yàn láti máa hùwà búburú, ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pa wọ́n run. Apá yìí máa jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń mọ̀ ti a bá ń ṣe rere tàbí búburú àti pé Jèhófà kò ní jẹ́ kí àwọn tó ń ṣe búburú borí àwọn tó ń ṣe rere.

NÍ APÁ YÌÍ

Ádámù àti Éfà Ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run

Kí ló mú kí igi kan dá yàtọ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì? Kí nìdí tí Éfà fi jẹ́ èso igi náà?

Kéènì Bínú Pa Àbúrò Rẹ̀

Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ẹ̀bọ́ Ébẹ́lì àmọ́ kò gba ti Kéènì. Nígbà tí Kéènì rí ohun tó ṣẹlẹ̀, inú bí i, ó sì hùwà búburú kan.

Nóà Kan Áàkì

Nígbà táwọn áńgẹ́lì burúkú kan fẹ́ àwọn obìnrin tó wà láyé, wọ́n bí àwọn ọmọ tó lágbára, tó sì máa ń fìyà jẹ àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń hùwà burúkú. Àmọ́ Nóà yátọ̀ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó sì máa ń ṣègbọràn sí i.

Èèyàn Mẹ́jọ La Ìparun Já

Òjò rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru. Ó ju ọdún kan lọ ti Nóà àti ìdílé rẹ̀ fi wà nínú áákì náà. Nígbà tó yá, wọ́n jáde kúrò nínú rẹ̀.