Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 3

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 3

Lẹ́yìn ìgbà tí Ọlọ́run fi omi pa àwọn èèyàn búburú run, Bíbélì dá orúkọ àwọn èèyàn díẹ̀ tó jọ́sìn Jèhófà. Lára wọn ni Ábúráhámù tí Bíbélì pè ní ọ̀rẹ́ Jèhófà. Kí nìdí tí Bíbélì fi pè é ní ọ̀rẹ́ Jèhófà? Tí o bá jẹ́ òbí, jẹ́ kí ọmọ rẹ rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an, ó sì fẹ́ ràn án lọ́wọ́. Bíi ti Ábúráhámù àti àwọn olóòótọ́ míì bíi Lọ́ọ̀tì àti Jékọ́bù, a lè bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Ó sì dá wa lójú pé Jèhófà máa mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ.

NÍ APÁ YÌÍ

Ilé Gogoro Bábélì

Àwọn èèyàn fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí ó máa ga dé ọ̀run. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi da èdè wọn rú?

Ábúráhámù àti Sárà Ṣègbọràn sí Ọlọ́run

Kí ló mú kí Ábúráhámù àti Sárà fi ìlú wọn sílẹ̀ láti lọ máa gbé nínú àgọ́ nílẹ̀ Kénáánì?

Sárá Bímọ Nígbà Tó Di Arúgbó!

Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa mú ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ? Ṣé ìpasẹ̀ Ísákì ni tàbí Íṣímáẹ́lì?

Rántí Ìyàwó Lọ́ọ̀tì

Ọlọ́run mú kí iná àti imí ọjọ́ rọ̀ sórí ìlú Sódómù àti Gòmórà. Kí ló dé tí Ọlọ́run fi pa àwọn ìlú yẹn run? Kí nìdí tó fi yẹ ká rántí ìyàwó Lọ́ọ̀tì?

Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò

Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Jọ̀ọ́, mú ọmọ kan ṣoṣo tí o ní, ẹ jọ lọ sí orí òkè kan ní Móráyà kí o sì fi ọmọ náà rúbọ.’ Báwo ni Ábúráhámù ṣe máa kojú ìdánwò ìgbàgbọ́ yìí?

Jékọ́bù Rí Ogún Gbà

Ísákì àti Rèbékà bí ìbejì, wọ́n sì sọ wọ́n ní Ísọ̀ àti Jékọ́bù. Torí pé Ísọ̀ ní àkọ́bí, òun ló yẹ kó gba ogún ìdílé wọn. Kí nìdí tó fi sọ ogún yẹn nù torí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré?

Jékọ́bù àti Ísọ̀ Parí Ìjà Wọn

Kí ni Jékọ́bù ṣe tó fi rí ìbùkún gbà lọ́dọ̀ áńgẹ́lì kan? Báwo ni òun àti Ísọ̀ ṣe parí ìjà wọn?