Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 4

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 4

Apá yìí máa jẹ́ ká mọ̀ nípa Jósẹ́fù, Jóòbù, Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Gbogbo wọn fara da àwọn ìṣòro tí Èṣù gbé kò wọ́n. Wọ́n fìyà jẹ àwọn kan, wọ́n sì sọ àwọn míì sí ẹ̀wọ̀n. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n sọ àwọn kan di ẹrú, àwọn míì sì pàdánù àwọn èèyàn wọn. Síbẹ̀, Jèhófà dáàbò bò wọ́n ní onírúurú ọ̀nà. Tí o bá jẹ́ òbí, ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè rí i bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yẹn ṣe jẹ́ olóòótọ́ láìka ìyà tí wọ́n jẹ.

Jèhófà lo ìyọnu mẹ́wàá [10] láti fi hàn pé òun lágbára ju àwọn òrìṣà tí àwọn ọmọ Íjíbítì ń bọ. Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ rí bí Jèhófà ṣe dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láyé àtijọ́ àti bó ṣe ń dáàbò bò wọ́n lónìí.

NÍ APÁ YÌÍ

Ẹrú Tó Ṣègbọràn sí Ọlọ́run

Jósẹ́fù ṣe ohun tó tọ́ ṣùgbọ́n ó jìyà gan an. Kí ló dé?

Jèhófà Kò Gbàgbé Jósẹ́fù

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jósẹ́fù jìnnà sáwọn ẹbí rẹ̀, Jèhófà dúró tì í.

Ta Ni Jóòbù?

Ó ṣègbọràn sí Jèhófà kódà nígbà tó ní ìṣòro.

Mósè Pinnu Láti Jọ́sìn Jèhófà

Ohun tí màmá Mósè ṣe ló gba ẹ̀mí Mósè là ní kékeré.

Iná Ń Jó Lára Igi Kékeré Kan

Kí ló dé tí iná yẹn kò fi jó igi náà run?

Ìyọnu Mẹ́ta Àkọ́kọ́

Fáráò fa àjálù bá àwọn èèyàn rẹ̀ torí pé ó jẹ́ agbéraga.

Àwọn Ìyọnu Mẹ́fà Tí Ó Tẹ̀ Lé E

Báwo ni àwọn ìyọnu mẹ́fà yìí ṣe yàtọ̀ sí mẹ́ta àkọ́kọ́?

Ìyọnu Kẹwàá

Ìyonu yìí burú débi pé ara Fáráò kò lè gbà á, ó sì dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀.

Iṣẹ́ Ìyanu ní Òkun Pupa

Fáráò la àwọn ìyọnu mẹ́wàá já, àmọ́ ṣé ó ye iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run ṣe yìí?