Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 5

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 5

Oṣù méjì lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Òkun Pupa kọjá, wọ́n dé Òkè Sínáì. Níbẹ̀, Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú pé wọ́n máa jẹ́ èèyàn òun. Ó dáàbò bò wọ́n, ó sì pèsè gbogbo ohun tí wọ́n nílò. Bí àpẹẹrẹ, ó fún wọn ní mánà, kò jẹ́ kí aṣọ wọn gbó, ó sì tún fún wọn níbi tó dára láti gbé. Tí o bá jẹ́ òbí, jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ mọ ìdí tí Jèhófà fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin, àgọ́ ìjọsìn àti àwọn àlùfáà. Jẹ́ kí wọ́n rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká mú ìlérí wa ṣẹ, ká ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì jẹ́ adúrósinsin sí Jèhófà.

NÍ APÁ YÌÍ

Wọ́n Ṣèlérí fún Jèhófà

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣèlérí kan fún Ọlọ́run nígbà tí wọ́n wà ní Òkè Sínáì.

Wọn Kò Mú Ìlérí Wọn Ṣẹ

Nígbà tí Mósè lọ gba òfin mẹ́wàá náà lórí òkè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hùwà burúkú.

Wọ́n Kọ́ Àgọ́ Ìjọsìn

Inú àgọ́ pàtàkì yìí ni apótí májẹ̀mú wà.

Àwọn Amí Méjìlá

Jóṣúà àti Kálébù yàtọ̀ sáwọn ọkùnrin mẹ́wàá tó kù tí wọ́n rán lọ ṣe amí ilẹ̀ Kénáánì.

Wọ́n Tako Jèhófà

Kórà, Dátánì, Ábírámù àti àwọn 250 mí ì kò mọ òtítọ́ pàtàkì kan nípa Jèhófà.

Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Báláámù Sọ̀rọ̀

Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí ẹnì kan tí Báláámù kò lè rí.