Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 6

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 6

Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àgọ́ ìjọsìn ni wọ́n ti máa ń jọ́sìn Jèhófà. Àwọn àlùfáà máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Ọlọ́run, àwọn onídàájọ́ sì máa ń darí wọn. Apá yìí máa jẹ́ ká rí i pé ohun tí ẹnì kan bá ṣe lè ṣe àkóbá fún àwọn míì tàbí kó ṣe wọ́n láǹfààní. Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ló gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì tún nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn. Kọ́ ọmọ rẹ nípa Dèbórà, Náómì, Jóṣúà, Hánà, ọmọ Jẹ́fútà àti Sámúẹ́lì. Jẹ́ kó rí i pé àwọn ìpinnu tí wọ́n ṣe nípa lórí àwọn míì. Tẹnu mọ́ ọn pé àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì pàápàá irú bíi Ráhábù, Rúùtù, Jáẹ́lì àti àwọn ará Gíbéónì pinnu láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí wọ́n rí i pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn.

NÍ APÁ YÌÍ

Jèhófà Yan Jóṣúà

Ọlọ́run fún Jóṣúà ní àwọn ìtọ́ni tó ṣàǹfààní fáwa náà lónìí.

Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́

Ògiri Jẹ́ríkò wó lulẹ̀. Àmọ́ ilé Ráhábù dúró bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara ògiri yẹn ni wọ́n kọ́ ọ mọ́.

Joshua and the Gibeonites

Jóṣúà gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Oòrùn, dúró sójú kan!” Ǹjẹ́ Ọlọ́run gbọ́ àdúrà rẹ̀?

Aṣáájú Tuntun àti Obìnrin Onígboyà Méjì

Lẹ́yìn tí Jóṣúà kú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn òrìṣà. Àwọn ọ̀tá wá ni wọ́n lára, àmọ́ Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́ nípasẹ̀ Bárákì, Dèbórà tó jẹ́ wòlí ì àti Jáẹ́lì.

Rúùtù àti Náómì

Àwọn obìnrin méjì tí ọkọ wọn ti kú pa dà sí Ísírélì. Ọ̀kan tó ń jẹ́ Rúùtù lọ ṣiṣẹ́ ní oko, Bóásì sì ṣàkíyèsí rẹ̀.

Gídíónì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Mídíánì

Nígbà táwọn ará Mídíánì fayé ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Báwo làwọn ọmọ ogun Gídíónì ṣe ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá 135,000?

Hánà Gbàdúrà Pé Kí Ọlọ́run Fún Òun ní Ọmọkùnrin

Ẹlikénà mú Hánà, Pẹ̀nínà àtàwọn ọmọ rẹ̀ lọ jọ́sìn ní àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò. Níbẹ̀, Hánà gbàdúrà fún ọmọkùnrin. Lẹ́yìn ọdún kan, ó bí Sámúẹ́lì.

Ìlérí Tí Jẹ́fútà Ṣe

Ìlérí wo ni Jẹ́fútà ṣe, kí sì nìdí? Kí ni ọmọbìnrin Jẹ́fútà ṣe nígbà tó gbọ́ nípa ìlérí bàbá rẹ̀?

Jèhófà Bá Sámúẹ́lì Sọ̀rọ̀

Élì Àlùfáà Àgbà ní ọmọkùnrin méjì tó ń sìn ní àgọ́ ìjọsìn, àmọ́ wọn kò pa òfin Ọlọ́run mọ́. Sámúẹ́lì yàtọ̀ ní tirẹ̀. Lálẹ́ ọjọ́ kan, Jèhófà bá Sámúẹ́lì sọ̀rọ̀.

Jèhófà Sọ Sámúsìnì Di Alágbára

Ọlọ́run mú kí Sámúsìnì lágbára láti bá àwọn Filísínì jà. Sámúsìnì wá ṣèpinnu tí kò dára, àwọn Filísínì sì mú un.