Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 8

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 8

Jèhófà bù kún Sólómọ́nì gan-an, ó fún un ní ọgbọ́n, ó sì jẹ́ kó kọ́ tẹ́ńpìlì fún òun. Àmọ́ nígbà tó yá, Sólómọ́nì fi Jèhófà sílẹ̀. Tí o bá jẹ́ òbí, ṣàlàyé fún ọmọ rẹ bí ìjọsìn òrìṣà ṣe mú kí Sólómọ́nì fi Jèhófà sílẹ̀. Ìjọba Ísírẹ́lì pín sí méjì, àwọn ọba búburú tó sì jẹ mú kí àwọn èèyàn náà máa jọ́sìn òrìṣà. Ní àkókò yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì Jèhófà ni wọ́n fìyà jẹ tí wọ́n sì pa. Jésíbẹ́lì tó jẹ́ ayaba tún mú kí àwọn èèyàn jọ́sìn àwọn òrìṣà burúkú. Nǹkan burú gan-an fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àkókò yìí. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lásìkò yẹn. Lára wọn ni Ọba Jèhóṣáfátì àti wòlíì Èlíjà.

NÍ APÁ YÌÍ

Wọ́n Kọ́ Tẹ́ńpìlì fún Jèhófà

Ọlọ́run gbọ́ àdúrà Sólómọ́nì, ó sì fún un ní àwọn nǹkan dáradára.

Ìjọba Ísírẹ́lì Pín sí Méjì

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò sin Jèhófà mọ́.

Ìṣẹ̀lẹ̀ kan Lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì

Ta ni Ọlọ́run tòótọ́? Jèhófà ni àbí Báàlì?

Jèhófà Fún Èlíjà Lókun

Ǹjẹ́ o rò pé ó lè fún ìwọ náà lókun?

Ọmọkùnrin Opó kan Jíǹde

Iṣẹ́ ìyanu méjì ṣẹlẹ̀ nínú ilé kan!

Ọlọ́run Fìyà Jẹ Ayaba Búburú Kan

Jésíbẹ́lì gbìmọ̀ láti pa ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ń jẹ́ Nábọ́tì kó lè gba ọgbà àjàrà rẹ̀! Jèhófà Ọlọ́run rí ìwà ìkà àti ìwà ìrẹ́jẹ yẹn.

Jèhófà Gbèjà Jèhóṣáfátì

Ọba Jèhóṣáfátì gbàdúrà sí Ọlọ́run nígbà táwọn ọ̀tá gbógun ti ilẹ̀ Júdà.