ORIN 3
Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa
-
1. A ní ìrètí iyebíye
tí à ń sọ fáráyé.
Ìrètí tó ń mórí wa wú,
lo fún wa, Jèhófà.
Ṣùgbọ́n tíṣòro bá ti pọ̀ jù,
ṣe nìbẹ̀rù máa ń bò wá.
Ìrètí wa tó lágbára
sì lè wá máa kú lọ.
(ÈGBÈ)
Agbára wa àti
Olùpèsè wa;
A gbọ́kàn lé ọ, Jèhófà.
À ń wàásù, à ń kọ́ni,
ọkàn wa balẹ̀
Torí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.
-
2. Jọ̀ọ́, Jèhófà Olùtùnú wa,
Jẹ́ ká máa rántí pé,
Gbogbo ìgbà tá a níṣòro
lo máa ń tù wá nínú.
Èyí ló sì mú ká lókun gan-an
tírètí wa fi ń sọjí;
Tá a fi lè fìgboyà sọ̀rọ̀
nípa orúkọ rẹ.
(ÈGBÈ)
Agbára wa àti
Olùpèsè wa;
A gbọ́kàn lé ọ, Jèhófà.
À ń wàásù, à ń kọ́ni,
ọkàn wa balẹ̀
torí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.
(Tún wo Sm. 72:13, 14; Òwe 3:5, 6, 26; Jer. 17:7.)