ORIN 6
Ọ̀run Ń Polongo Ògo Ọlọ́run
(Sáàmù 19)
-
1. Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà táà ńrí
Kéde ògo rẹ̀ gan-an
lójú òfuurufú.
Ojoojúmọ́ ni wọ́n ńfìyìn fún ọ,
Ìràwọ̀ ń fagbára rẹ hàn,
Ìfẹ́ àtọgbọ́n rẹ.
-
2. Òfin rẹ pé, ó ń mú káyé wa dára.
Tọmọdé tàgbà ni
o sì ń fi ṣamọ̀nà.
Ìṣàkóso rẹ tọ́, òdodo ni.
Òfin rẹ mọ́, Ọ̀rọ̀ rẹ ń ṣẹ,
Wọ́n ńṣe wá láǹfààní.
-
3. Àwọn òfin rẹ máa wúlò títí láé.
Tí a bá ń pa wọ́n mọ́,
wọ́n máa dáàbò bò wá.
Èyí ń fi hàn pé a níbẹ̀rù rẹ.
Ògo, iyì, ọlá yẹ ọ́;
A gbórúkọ rẹ ga.
(Tún wo Sm. 111:9; 145:5; Ìfi. 4:11.)