Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 8

Jèhófà Ni Ibi Ààbò Wa

Jèhófà Ni Ibi Ààbò Wa

(Sáàmù 91)

  1. 1. Jèhófà ni ààbò wa.

    Ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.

    Òjìji rẹ la sá di,

    A ò ní sá kúrò láé.

    Torí a mọ̀ pé wàá gbèjà

    Àwọn tó bá gbára lé ọ.

    Jèhófà l’Olùṣọ́ wa;

    Olódodo, olóòótọ́ ni.

  2. 2. Jèhófà máa ń dáàbò bo

    Àwọn olódodo

    Àti ọlọ́kàn tútù;

    Kò ní pa wọ́n tì láé.

    Torí náà, kò yẹ ká bẹ̀rù

    Torí ìyọnu àjálù.

    Òun yóò máa dá wa nídè

    Kúrò lọ́wọ́ ẹni ibi.

  3. 3. Ó ń tọ́ wa, ó sì ńṣọ́ wa

    Ká má kó sídẹkùn.

    Ó ń fún wa lókun ká lè

    Máa kojú àtakò.

    Kò sí ìdí kankan fún wa

    Láti bẹ̀rù ohunkóhun.

    Jèhófà ni ààbò wa,

    Yóò dáàbò bò wá títí láé.