Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 10

Ẹ Yin Jèhófà Ọlọ́run Wa!

Ẹ Yin Jèhófà Ọlọ́run Wa!

(Sáàmù 145:12)

  1. 1. Ẹ fìyìn fún Ọlọ́run wa!

    Sọ orúkọ rẹ̀ fáráyé!

    Ẹ kìlọ̀ fún gbogbo èèyàn,

    Pé ọjọ́ ńlá rẹ̀ ti sún mọ́lé.

    Torí ìṣàkóso ọmọ rẹ̀ ti

    Bẹ̀rẹ̀ bó ti ṣe sọ tẹ́lẹ̀.

    A ó ròyìn rẹ̀ f’ónírúurú èèyàn,

    Àti ìbùkún tó ń mú bọ̀!

    (ÈGBÈ)

    Ẹ fìyìn fún Ọlọ́run wa!

    Ròyìn ọlá ńlá rẹ̀ fáráyé!

  2. 2. Ẹ kọrin! Fi orin ayọ̀

    Gbórúkọ ńlá rẹ̀ lárugẹ!

    Ọkàn wa kún fún ọpẹ́ gan-an,

    À ń fìgboyà kéde ògo rẹ̀.

    Jèhófà tóbi, iṣẹ́ rẹ̀ pọ̀ gan-an,

    Síbẹ̀ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.

    Oore rẹ̀ pọ̀ gan-an, ó máa ńtọ́jú wa,

    Ó sì máa ń gbọ́ àdúrà wa.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ fìyìn fún Ọlọ́run wa!

    Ròyìn ọlá ńlá rẹ̀ fáráyé!