Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 11

Ìṣẹ̀dá Ń Yin Ọlọ́run

Ìṣẹ̀dá Ń Yin Ọlọ́run

(Sáàmù 19)

  1. 1. Àwọn ìṣẹ̀dá ń yìn ọ́, Jèhófà,

    Wọ́n pọ̀ púpọ̀ lójú sánmà lókè.

    Wọ́n ń ròyìn ògo àtagbára rẹ

    Fún aráyé láìsọ ọ̀rọ̀ kankan.

    Wọ́n ń ròyìn ògo àtagbára rẹ

    Fún aráyé láìsọ ọ̀rọ̀ kankan.

  2. 2. Àwọn àṣẹ rẹ ńsọni d’ọlọ́gbọ́n,

    Wọ́n ń dáàbò bò wá ní gbogbo ọ̀nà.

    Wọ́n ń ṣe tọmọdé tàgbà láǹfààní;

    Wọ́n wúlò ju wúrà iyebíye.

    Wọ́n ń ṣe tọmọdé tàgbà láǹfààní;

    Wọ́n wúlò ju wúrà iyebíye.

  3. 3. Asán kọ́ layé àwa tá a mọ̀ ọ́,

    Ọ̀rọ̀ rẹ ń mú káyé wa nítumọ̀.

    Ọlá ńlá lo dá àwọn tó mọ̀ ọ́,

    Àwọn tó ń sorúkọ rẹ di mímọ́.

    Ọlá ńlá lo dá àwọn tó mọ̀ọ́,

    Àwọn tó ń sorúkọ rẹ di mímọ́.