Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 12

Jèhófà, Ọlọ́run Atóbilọ́lá

Jèhófà, Ọlọ́run Atóbilọ́lá

(Ẹ́kísódù 34:6, 7)

  1. 1. Ògo àtìyìn yẹ ọ́, Jèhófà,

    Ẹniire tó ń ṣòdodo

    Ní gbogbo ọ̀nà lo jẹ́.

    Agbára, ọgbọ́n àtìfẹ́ rẹ pọ̀,

    Ọlọ́run ayérayé.

  2. 2. Bàbá, àánú rẹ máa ńtù wá lára.

    O máa ń gbọ́ àdúrà wa

    Báa tilẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.

    Ò ń gbẹ́mìí wa ró, o sì tún ńkọ́ wa;

    Atóófaratì ni ọ́!

  3. 3. Àwọn ẹ̀dá lọ́run àti láyé,

    Wọ́n ń forin yìn ọ́ lógo;

    Àwa náà yóò máa yìn ọ́.

    Atóbilọ́lá, jọ̀ọ́ gba ìyìn wa.

    Tọkàntọkàn là ń yìn ọ́.