Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 14

Ẹ Yin Ọba Tuntun Tó Jẹ Lórí Ayé

Ẹ Yin Ọba Tuntun Tó Jẹ Lórí Ayé

(Sáàmù 2:12)

  1. 1. Jésù Kristi àti àwọn

    ẹni àmì òróró

    Ń kó ọ̀pọ̀ èèyàn jọ láti

    inú gbogbo ‘rílẹ̀-èdè.

    Ìjọba náà ti wà lọ́run,

    yóò mú ìfẹ́ Jáà ṣẹ láyé.

    Ìrètí yìí mà ṣeyebíye!

    Ó ń tù wá nínú, à ń láyọ̀.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ yin Ọlọ́run wa; Ẹ yin Jésù Kristi,

    Olúwa, Ọba àwọn ọba.

    Gbogbo wa kọ́wọ́ ti Ìjọba rẹ̀,

    A ó sì máa yìn ín níṣọ̀kan.

  2. 2. À ń fìyìn f’Ónídàájọ́ wa

    tí yóò mú ìgbàlà wá.

    Ọmọ Aládé Àlàáfíà

    ti ń ṣàkóso ní ọ̀run.

    Yóò jí àwọn òkú dìde;

    Yóò mú ‘bẹ̀rù kúrò láyé.

    À ń retí àkókò yìí, kó dé.

    Gbogbo ayé ló máa láyọ̀!

    (ÈGBÈ)

    Ẹ yin Ọlọ́run wa; Ẹ yin Jésù Kristi,

    Olúwa, Ọba àwọn ọba.

    Gbogbo wa kọ́wọ́ ti Ìjọba rẹ̀,

    A ó sì máa yìn ín níṣọ̀kan.