Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 29

À Ń Jẹ́ Kí Orúkọ Wa Máa Rò Wá

À Ń Jẹ́ Kí Orúkọ Wa Máa Rò Wá

(Àìsáyà 43:10-12)

  1. 1. Jèhófà ológo, Olódùmarè,

    Orísun òótọ́, ọlọ́gbọ́n pípé.

    Òdodo, agbára àtìfẹ́ rẹ pọ̀;

    Ọba Aláṣẹ láyé àtọ̀run.

    Àwa èèyàn rẹ ń láyọ̀ báa ṣe ńsìn ọ́.

    À ń fayọ̀ sọ òótọ́ Ìjọba rẹ.

    (ÈGBÈ)

    Àǹfààní ńlá ni pé a j’Ẹlẹ́rìí rẹ.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ kí orúkọ wa máa rò wá.

  2. 2. Ìfẹ́ ń mú ká máa ṣiṣẹ́ ìsìn mímọ́.

    Ó ń mú ká ṣiṣẹ́ pọ̀ lálàáfíà.

    Ẹ̀kọ́ òtítọ́ ń mú káyé wa dára;

    Inú wa ń dùn bá a ṣe ń gbógo rẹ yọ.

    Ẹlẹ́rìí Jèhófà laráyé ń pè wá,

    Èyí ń jẹ́ ká lè fi kún iyì rẹ.

    (ÈGBÈ)

    Àǹfààní ńlá ni pé a j’Ẹlẹ́rìí rẹ.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ kí orúkọ wa máa rò wá.